Àtunṣe máa débá ìlànà ìkọ́lé l'Ékoo-Sanwó-Olú



Ọlaide Gold

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti fọkan awọn abanikọle balẹ pe wọn maa ni anfaani sawọn ohun amayedẹrun to le faaye gba awọn olokoowo ile lati ṣiṣẹ wọn nirọrun.

Nibi ipatẹ idokoowo ilẹ ẹlẹẹkarun iyẹn Lagos Real Estate Marketplace Conference and Exhibitions, to waye  lọjọ Tuside ni gbọngan Eko Hotels ni Sanwo-Olu ti sọrọ naa bakan naa lo fi dawọn loju pe, abajade awọn alakalẹ ijọba maa rọju fun wọn lati ṣiṣẹ.

Eto naa tiwọn pe akọri ẹ ni "Ṣiṣe atunṣe odiwọn ilẹ ati atunṣe iṣẹ abanikọle" ni
gomina ti jẹ ko di mimọ pe, bawọn eeyan ṣe n kọle kaakiri tiwọn wọn o si bikita boya ori koto idaminu lawọn kọle si gbero bẹẹ ni ijọba Eko ti ṣetan lati ṣe atunṣe.

Sanwo-Olu tẹsiwaju ninu ọrọ ẹ pe, iṣẹ abanikọle n fẹ amojuto toripe ẹni to n yọ  bukọọku ta ti sọrọ ẹ di abanikọle toripe o lowo lọwọ ṣugbọn ko bikita lati gbawọn akọṣẹmọṣẹ tiwọn nimọ nipa ile kikọ titi to fi pari iṣẹ. O lawọn iru ile bẹẹ kii tọjọ to
fi maa dawo to si fi ẹmi awọn eeyan sinu ewu nitoripe  ipilẹ rẹ ti wọ latilẹ.

Ijọba ti ṣetan lati ṣe ojuṣe rẹ fun aabo araalu tori naa abanikọle gbọdọ jẹ akọṣẹmọṣẹ to ni iwe ẹri ijọba.

Gẹgẹ bi ọrọ ẹ, o dajupe a ma ṣe aṣeyọri lori eto ilana ile kikọ atawọn olokoowo ilẹ, a  ti gbiyanju fawọn araalu nipa pipese awọn ohun amayedẹrun, yaara ikawe fawọn ọmọ wa, kikọ ile olowo pọọku, eto irinna lori ilẹ, loju omi ati reluwe.
Bakan naa la ṣeranwọ fawọn araalu lori eto ọgbin, ṣiṣeranwọ kikọ nipa imọ ẹrọ fawọn ọdọ pẹlu eto ironilagbara fawọn, obinrin, awọn opo atawọn agbalagba.

Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Sanwó-Olú ṣèlérí ètò ìrànlọ́wọ́ láti sàmì àyájọ́ àwọn obìnrin lágbàáyé