Posts

Showing posts with the label News

Àtunṣe máa débá ìlànà ìkọ́lé l'Ékoo-Sanwó-Olú

Image
Ọlaide Gold Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti fọkan awọn abanikọle balẹ pe wọn maa ni anfaani sawọn ohun amayedẹrun to le faaye gba awọn olokoowo ile lati ṣiṣẹ wọn nirọrun. Nibi ipatẹ idokoowo ilẹ ẹlẹẹkarun iyẹn Lagos Real Estate Marketplace Conference and Exhibitions, to waye  lọjọ Tuside ni gbọngan Eko Hotels ni Sanwo-Olu ti sọrọ naa bakan naa lo fi dawọn loju pe, abajade awọn alakalẹ ijọba maa rọju fun wọn lati ṣiṣẹ. Eto naa tiwọn pe akọri ẹ ni "Ṣiṣe atunṣe odiwọn ilẹ ati atunṣe iṣẹ abanikọle" ni gomina ti jẹ ko di mimọ pe, bawọn eeyan ṣe n kọle kaakiri tiwọn wọn o si bikita boya ori koto idaminu lawọn kọle si gbero bẹẹ ni ijọba Eko ti ṣetan lati ṣe atunṣe. Sanwo-Olu tẹsiwaju ninu ọrọ ẹ pe, iṣẹ abanikọle n fẹ amojuto toripe ẹni to n yọ  bukọọku ta ti sọrọ ẹ di abanikọle toripe o lowo lọwọ ṣugbọn ko bikita lati gbawọn akọṣẹmọṣẹ tiwọn nimọ nipa ile kikọ titi to fi pari iṣẹ. O lawọn iru ile bẹẹ kii tọjọ to fi maa dawo to si fi ẹmi awọn eeyan sinu ewu nitori...