Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun
- Get link
- X
- Other Apps
Ọlaide Gold
Wamuwamu ni gbọngan NUT Pavilion Events Centre nilu Ikẹja nipinlẹ Eko kun lọjọ Satide to kọja, awọn ọmọ bibi ilu Oro nipinlẹ Kwara tiwọn fi ilu Eko ṣebugbe ni wọn lọ pade Ọba Ọlaniyi Ọyatoye,Titiloye Olufayọ keji, iyẹn Oloro tilu Oro to ṣẹṣẹ gun ori itẹ awọn baba nla rẹ.
Ọba Ọlaniyi Ọyatoye ninu ọrọ rẹ dupẹ lọwọ awọn ọmọ bibi ilu Oro ti wọn wa nibẹ lọjọ naa, kabiyesi wure aṣeyọri lẹnu iṣẹ ti ẹni kọọkan n ṣe, Oloro tuntun naa ni, ogunlọgọ eeyan ni wọn mọ ilu Oro pẹlu ipede ‘Owo ni e jẹ’ tori naa, owo ko ni i wọn lapo ẹnikọọkan atawọn afẹnifẹre wọn.
Siwaju si i, kabiyesi ṣeleri itẹsiwaju rere nilu Oro lasiko tiẹ, ọba alaye naa ni, gbogbo ẹbẹ awọn ọmọ oniluu loun ti gbọ bẹẹni igbesẹ lati fidi irẹpọ mulẹ ti n lọ labẹnu atipe didun lọsan yoo so laipẹ.
Bo tiẹ jẹ pe, wọn ni oye ọba naa di fa-n-fa laarin awọn ọmọ oye bii meloo kan, ko to bọ sọwọ idile Titiloye Olufayọ, tijọba ipinlẹ Kwara si ti gbọpa aṣe le e lọwọ gẹgẹ bi Alayeluwa Oloro tilu Oro.
Biba lawọn alẹnulọrọ atawọn ọtọkulu ilu Oro tiwọn n ṣiṣẹ aje l’Ekoo pẹjupesẹ sinu gbọngan naa lati fidunnu wọn han pe awọn ti lọba tuntun bakan naa lawọn kan lo anfaani naa lati sọ ẹdun ọkan wọn sita paapaa lori awọn nnkan ti wọn fẹ ki kabiyesi bawọn mojuto.
Imaamu Agba fun ilu Oro, Ọmọwe Taofik Sanusi, lo kọkọ fadura ṣide eto nilana ẹsin islam, lẹyin adura naa ni imaamu gba kabiyesi niyanju lati ko awọn eeyan mọra labẹ akoso bo ti wu ko ri bẹẹ lo gba a ladura pe, oore to sọlẹ sinu idile Titiloye Olufayọ ko ni bọ danu laṣẹ Edumare. Lẹyin naa ni, Pasitọ Rapheal Ogunwale naa gbadura nilana ẹsin kristẹni toun naa si ṣadura fun kabiyesi pe o ti fọmọde joye ki Olodumare jẹ ko fi agba lo o.
Ninu ọrọ Ọnarebu Damọla akọṣilẹ, agba oloṣelu kan nipinlẹ Kwara lo ti sọ pe,’’ loootọ awa naa du ipo ọba yii ṣugbọn o ti bọ sẹnikan lọwọ bayii nitori naa imọran mi fun kabiyesi wa ni pe, ki ọba wa tunbọ gbiyanju lati fa awọn tinu n bi mọra ṣugbọn ọmọ akin ki i ṣojo, ẹni to ba loun ko ni i ba oriade ṣe, ki kabiyesi ma fipa mu iru ẹni bẹẹ atipe ọdọ ni kabiyesi wa, o si gbọdọ bẹrẹ si i ṣiṣẹ ilọsiwaju aritọkasi nilu Oro nitori naa ki gbogbo ẹni tinu n bi gbe ibinu sẹgbẹ kan, itẹsiwaju ni ka jọ maa wa bayii.’’
Awọn alẹnulọrọ ilu Oro tiwọn tun wa nibẹ lọjọ naa ni, Ọnarebu Toyin Arẹmu, Olubagbamọran Agba fun gomina Babajide Sanwo-Olu lori eto irinna,awọn baalẹ kaakiri ilu Oro,Oloye Agba, Ibikunle Oyebamiji, Ọmọọba Adetoye Olowo,baba ọba ilu Oro, Eesa ilu Oro, Iya ọba ilu Oro,Oloye Florence Adebara ati Iyalode ilu Oro,Oloye Ṣẹrifat Kofoworọla Okelẹyẹ
- Get link
- X
- Other Apps
Comments
Post a Comment