Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa
Ọlaide Gold
Titi dasiko yii lọrọ naa ṣi n ṣe awọn eeyan ni kayeefi, paapaa julọ awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn lagbegbe Agege nipinlẹ Eko. Oluṣọ ijọ sẹlẹ kan, CCC Adeiyanu Parish ni Iyana Ipaja torukọ ẹ n jẹ, Alani John Ọlabamidele tawọn eeyan tun mọ si Alani-Fẹrẹbiẹkun ni wọn lo kọkọ da ija naa silẹ tawọn ọdọ fi sọ di nnkan mi-in mọ lọwọ.
Gẹgẹ baa ṣe gbọ, ajihinrere kan ninu ijọ naa torukọ ẹ n jẹ Taiwo Lasisi, ni wọn lo gbe turari lọ sori pẹpẹ ṣugbọn ti ọluṣọ gbe igba turari naa kuro nibẹ, iyẹn ni wọn lo bi ọmọkunrin naa ninu tija fi sọ. Ṣe ṣaaju akoko naa lawọn ọmọ ijọ ko ti fẹran oluṣọ wọn tuntun latigba ti wọn ti gbe de nitoripe wọn ni ṣeni oluṣọ naa ma n paṣẹ bi ologun, idi niyẹn tawọn ọmọ ijọ fi gbana oju ẹ lọjọ tija naa ṣẹlẹ.
Iroyin to tẹ wa lọwọ ni pe, nigba tiwọn n ṣe ikore loṣu kẹsan an ọdun yii nija naa ti bẹrẹ, wọn ni, bi oluṣọ ijọ naa tẹlẹ torukọ ẹ n jẹ Idowu Adelu ti wọn ti gbe lọ sijọ CCC Zion Santuary Parish, Oshodi wa bawọn yọ ayọ ikore, lawọn ọmọ ijọ bẹrẹ si i yẹ ọkunrin naa si tijo tayọ tiwọn tun na an lowo eyi ti wọn o ṣe fun oluṣọ wọn tuntun.
Ohun taa tun gbọ ni pe, Ogunjọ, Ọjọru, Wẹside, ti wọn n ṣe isin aanu nija naa ti burẹkẹ sii koda awọn tiwọn n gbe lagbegbe ijọ naa ni, ṣe lawọn kọkọ ro pe awọn ọmọ ganfe niwọn n gbena woju ara wọn bawọn ṣe n gburo igo bo ṣe n dun lakọlakọ koda wọn ni bo ba tiẹ jẹ pe, awọn ọmọ ganfe naa ni wọn n ja, ko yẹ kọrọ naa le to bẹẹ. Idi si niyẹn to fi ya wọn lẹnu pe awọn ọmọ ijọ Ọlọrun ni wọn n ja.
Lojuẹsẹ tawọn alaṣẹ ijọ sẹlẹ gbọ nipa ija naa ni wọn ti gbe ikọ akojanu ijọ dide ti wọn si gbe ijọ naa tipa titi ti iwadii yoo fi pari lori nnkan to fa a tiwọn fi sọ ijọ Ọlọrun di ibudo ijakadi.
Nigba ti aṣojukọrọyin Gbelegbọ ṣabẹwo si ijọ naa ladugbo Alagbaa, l’Agege lati ṣewadii bọrọ naa ṣe ri gan an, ọkunrin kan to pe orukọ ara rẹ ni Kẹhinde loun ni igbakeji oluṣọ ijọ naa, o ni bọrọ ṣe ri kọ niyẹn ṣugbọn oun o le ba oniwe iroyin sọrọ nitoripe awọn alaṣẹ ti da sọrọ naa latoke bẹẹ lofin ijọ o faaye gba oun lati sọrọ lori ẹ. Ọjọ kejilelogun oṣu kẹwaa ọdun yii ni wọn fi kọkọrọ awọn alaṣẹ ti ṣọọṣi naa pa.
Bẹ o ba gbagbe ninu oṣu kẹwaa kan naa lawọn alaṣẹ ijọ sẹlẹ ni ki wọn lọ ti ijọ sẹlẹ, Acts of Apostle Parish, to wa ni Ketu, Alapere,nilu Eko pa. Owo niwọn lo daja silẹ ninu ijọ ọhun, ẹgbẹrun marun miliọnu naira ti olu ijọ sẹlẹ fun ijọ naa lati ṣatunkọ ijọ niwọn lo daja silẹ, ikọ akojanu ti Akinbọde Adjovi, lewaju lo tijọ naa pa fun ogoji ọjọ ni ibamu pẹlu aṣẹ latoke.
Ko tan sibẹ o, lọjọ kọkanla oṣu kọkanla niroyin kan gba igboro kan nilu Ibadan, maalu meji tijọ sẹlẹ, Testimony Parish, lagbegbe Elerumoke-Ẹgbẹda nipinlẹ Ọyọ lawọn kan ji gbe salọ loru mọju lasiko tijọ naa n ṣepalẹmọ ikore wọn. Lori ikanni ibanidọrẹẹ ori ayelujara nijọ naa ti fi iroyin ọhun lede, ti wọn si n bẹbẹ fun iranlọwọ latọdun awọn ẹlẹyinju aanu fun ẹbun owo lati ra maalu mi-in fun ikore.
Awọn iṣẹlẹ ara ọtọ to waye ninu ijọ sẹlẹ lopin ọdun yii lawọn eeyan fi n beere pe, ki lo n sẹlẹ nijọ sẹlẹ toripe kinni ọhun ṣe tẹle-n-tẹle, bawọn kan ṣe n sọ pe, o yẹ ki wọn ti ri awọn iṣẹlẹ naa ninu ẹmi ki wọn si ti sọ ọ mọ awọn asọtẹlẹ tiwọn maa n sọ ni awọn kan sọ pe, Josẹfu ninu bibeli gan an alara ko ri i pe oun maa ṣẹwọn ṣugbọn ju gbogbo ẹ lọ, gẹgẹ bi ọrọ Kayọde Ajala, adari ẹka iroyin ijọ sẹlẹ, o ni, ki ija naa ma ba kọja nnkan ti apa ko ni ka ati fun aabo awọn ọmọ ijọ lawọn alaṣẹ ṣe gbe awọn ṣọọṣi naa tipa lati pẹtu sija naa ki nnkan le maa lọ deede bii atẹyinwa.
Comments
Post a Comment