Ọ̀rọ̀ ọba jíjẹ di wàhálà nílùú Igbóoyé,wọ́n ní Sanwó-Olú nìkan ló lè bá wa yanjú ẹ̀



Ọlaide Gold

Lọwọlọwọ bayii, ibẹrubojo lawọn araalu fi n rin nilu Igbooye nijọba ibilẹ onidagbasoke Eredo l'Ẹpẹ,ipinlẹ Ogun. ko si nnkan meji to fa a ju ọrọ ọba jijẹ lọ. 
Gẹgẹ bi nnkan tawọn araalu naa sọ, ọkunrin kan torukọ ẹ n jẹ Wasiu Musa Adebamọwọ ni o n da rukerodo silẹ, wọn ni ṣe lo  n sa gbogbo ipa to ni lati gbe aburo ẹ Ọgbẹni Rasak Musa Adebamọwọ sori itẹ gẹgẹ bi ọba leyi tawọn eeyan koro oju si.
Ninu ipade tawọn ẹbi ṣe pẹlu awọn oniroyin lọjọ Ẹti Furaide to kọja ni ọkan lara awọn agba ilu, to tun jẹ akọwe idile Erelu, Ọtunba Anthony Oguntimẹhin, ti ṣalaye pe, idile mẹrẹẹrin to n jọba ni Igbooye lo yan ọba to wa lori itẹ lọwọlọwọ iyẹn Ọba Michael Gbadebọ Ọnakọya beeni kabiyesi gun ori itẹ baba nla rẹ lẹyin tawọn afọbajẹ pari gbogbo igbesẹ to yẹ. "ohun kan to daju ni ilẹ yoruba ni pe, bi ọba kan ko ba ku,ọba mi-in o le jẹ."
Bakan naa ni, Ọgbẹni Julius Adenuga lawal, adari kan ninu ẹbi Ewade ni, bo tiẹ jẹpe ẹjọ ṣi wa ni kọọtu nibiti, Ọba Micheal Gbadebọ Ọnakọya ti gbe ẹjọ rẹ dewaju ile ẹjọ to ga julọ nilẹẹwa ṣugbọn ṣeni ẹka kan lara idile Ewade eyi ti  Ọgbẹni Wasiu Musa Adebamọwọ,ẹni to tun jẹ ọga kan lẹka ileeṣẹ ijọba to n mojuto eto idajọ l'Eko n dari to si n lo ọwọ agbara lati pa ilana tilu n tẹle lati yan ọba ti, to si fẹẹ fi aburo ẹ jọba.
O ni, gbogbo ẹbi lo koro oju si ete ati ọgbọn ẹwẹ ti Wasiu Adebamọwọ n da lati fi aburo ẹ sori oye koda wọn ni awọn araalu ti kọwe ranṣẹ sijọba ipinlẹ Eko lọpọ igba eyiti fi wọn ṣalaye awọn igbesẹ iyansipo ọba nilu naa ti Adebamọwọ n gbe ṣugbọn tiwọn o ri esi iyẹn lo jẹ ki wọn sọ pe, o jọ bi ẹnipe ẹnikan lo n dena iwe naa ti ko fi de ọdọ gomina, idi si niyẹn tawọn fi ke gbajare sita kiwọn ma ba gbe ru wọn latẹyin.
Gẹgẹ bi alakalẹ iyansipo ọba, gbogbo idile to n jọba nilu Igbooye lo gbọdọ kede ọmọ oye wọn setigbọ gbogbo eeyan, ọmọ oye to kaju iwọn ti araalu n fẹ lo ma bọ sori itẹ. 
Awọn afọbajẹ ilu jẹ akojọpọ awọn adari idile oye kọọkan ati Olisa ilu Igbooye,awọn naa ni wọn ma fi ọmọ oye tori ṣe loore han gbogbo ilu tiwọn si ma faa le ijọba lọwọ ṣugbọn lọwọlọwọ govern bayii, ipo Olisa ṣi ṣofo latigba Oloye Fatayi Mustapha ṣilẹwọ lọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kẹrin, ọdun 2017.

Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Àjọ ẹlẹ́yinjú àánú KAF ṣèrànwọ́ fáwọn aráàlú nilùú Ilé-Ifẹ̀

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa