Àjọ ẹlẹ́yinjú àánú KAF ṣèrànwọ́ fáwọn aráàlú nilùú Ilé-Ifẹ̀
Ninu oṣu kẹjọ ọdun 2020 ni wọn da ajọ naa silẹ lorileede Naijiria pẹlu ipinnu lati maa ran awọn eeyan lọwọ nipa fifojusun awọn ọdọ,opo atawọn alaini lati ṣeranwọ owo iṣẹ fun wọn, fifunwọn ni ounjẹ bakan naa ni wọn ṣe ironilagbara fun wọn. Ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu keje ọdun yii ni wọn ṣe ifilọlẹ ajọ naa pẹlu ayẹyẹ ọlọjọ mẹrin to bẹrẹ lọjọru Wẹside, ọjọ kẹrindinlọgbọn ni olu ileeṣẹ ajọ naa iyẹn KAF secretariate to wa ni adugbo Okesoda nilu Ile-Ifẹ nipinlẹ Ọṣun.
Ipade pẹlu awọn oniroyin lo kọkọ waye nibiti wọn ti ṣalaye nnkan ti ajọ naa da le lori atawọn iṣẹ ẹlẹyinju aanu tajọ naa ti ṣe fawọn oniroyin bakan naa ni irinafẹ to waye lọjọ keji tiiṣe Tọside, Ọjọ kẹtadinlọgbọn, eyi ti wọn fi rin lọ si olu ileeṣẹ ajọ naa nibi tawọn eeyan ti jẹ anfaani ayẹwo ilera ọfẹẹ, itọju awọn aisan kọọkan ati ẹbun ounjẹ ọfẹẹ loriṣiiriṣii. Ọjọ Ẹti Furaide ni ifẹsẹwọnsẹ ere bọọlu ọrẹsọrẹ waye ninu ọgba Oduduwa college laarin St David Grammar school ati St Philips grammar school nilu Ile-Ifẹ nibiti ileewe St David Grammar school ti jawe ewuro soju ikọ agbabọọlu keji pẹlu ayo meji si odo.
Ọmọọba Aderonkẹ Adegoke lo gbe ife ẹyẹ naa le ikọ agbabọọlu to jawe olubori lọwọ. Ọjọ Abamẹta Satide, ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kẹfa ọdun yii ni aṣekagba eto naa waye ni agbala igbafẹ nla, Ife Grand Resort. Awọn eeyan pataki laarin ilu atawọn lọbalọba pẹlu awọn oniṣowo pataki ni wọn wa nibi ayẹyẹ naa nibi tawọn ọlọja ti maa bẹrẹ sii gba owo iranwọ lati kun ọja wọn.
Comments
Post a Comment