Òfin Èkó: Kí nǹkan lè yé àwọn aráàlú ni a ṣe fẹ́ẹ́ tú òfin sí èdè abínibí -Adéníji
- Get link
- X
- Other Apps
Ọlaide Gold
Gomina Sanwo-Olu lo ṣefilọle Lateef Jakande Leadership Academy lọdun meji sẹyin ni iranti gomina oloṣelu akọkọ nipinlẹ Eko, Oloye Lateef Kayọde Jakande, ẹka ikẹkọọ naa wa fawọn ọdọ lati ṣawari ọgbọn atinuda wọn ati lati tọ wọn sọna ninu irinajo igbesi aye wọn ki wọn le wulo fun ipinlẹ Eko ati Orileede Naijiria lapapọ.
Lati fidi ọgbọn atinuda mulẹ ni ipin kan lẹka ẹkọ naa eyi ti wọn pe ni ‘Team Ace’ ṣe ṣiṣẹ lori ‘Ofin Eko’,wọn lo ṣe pataki fawọn olugbe ipinlẹ naa lati mọ nipa ofin to n dari wọn atipe ki ẹnikẹni ma le fi dudu pe pupa fun wọn. Ipin naa gẹgẹ bi alaye ti adari wọn, Ọgbẹni Usman Adeniji ṣe , ileewe naa ti mu ki ofin Eko rọrun lati mọ fawọn araalu bẹẹ lo ti wa ni arọwọto wọn bayii bi wọn ba ti le tẹlẹ ilana ti wọn ti la kalẹ ilana fun wọn,lọgan ni ofin Eko ma jade bi wọn ba tẹ www.ekolaw.com
O ṣalaye siwaju sii pe, agbekalẹ ofin Eko wa ni ibamu pẹlu akitiyan lati mu adinku ba iṣoro tawọn eeyan n koju labala ofin
Ni bayii, eto ti wa lati tu ofin Eko palẹ si ede abinibi ko le ye awọn araalu bi wọn ba kaa lẹka ede wọn. Awọn ofin bii, ẹtọ ọmọde labẹ ofin, ofin onile ati ayalegbe,ofin ọja, ofin ẹtọ ọmọniyan,ofin irinna ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Igbesẹ naa waye lati tọ awọn eeyan sọna nilana ofin nitori ofin ko faaye gba iwa omugọ atipe o ma jẹ kiwọn mọ ẹtọ wọn labẹ ofin.
Lateef Jakande Leadership Academy ti ṣetan lati ṣiṣẹpọ pẹlu awọn ẹka ofin kọọkan atawọn eekan laarin ilu lati rii dajupe ofin naa wa ni arọwọto awọn araalu.
Lakotan, Adeniji sọ pe, awọn ofin kan wa ti igba ti kọja lori ẹ ti atunṣe si ti deba idi niyẹn tawọn eeyan ipinlẹ Eko ṣe gbọdọ mọ nipa ofin tuntun ki wọn si ma ṣe amulo rẹ- Get link
- X
- Other Apps
Comments
Post a Comment