Oluwaloni ṣedaro alaga kansu to ku lojiji l'Ekoo
Inu ipayinkeke ati ibanujẹ ọkan ni gbogbo ara agbegbe Ayobo-Ipaja Local Council Development Area (LCDA) wa, latari iku alaga kẹta to jẹ ni agbegbe naa, Hon. Chief (Mrs.) Bolatito Shobowale. Ẹni to jẹ adele alaga Ayobo-Ipaja LCDA, Otunba Ladi Oluwaloni (OLO 1), lọ sọrọ naa di mimọ, pẹlu ibanujẹ ọkan ni Oluwaloni fi kede iku oloogbe Shobowale ni ọjọ Ẹti ọsẹ yii. O ni, iku arabinrin naa jẹ kayeefi fun awọn ati pe iṣẹlẹ to bani lọkan jẹ gidi ni iku naa jẹ,nitori oloogbe jẹ ẹni to da ni awujọ awọn. Oluwaloni ṣe apejuwe Shobowale gẹgẹ bi eniyan rere to fẹ ilọsiwaju ilu, o ni oloogbe naa ki i ṣe olori nikan, o ni o jẹ alatilẹyin rere, igi lẹyin ọgba ọpọlọpọ awọn eeyan lo tun jẹ pẹlu. Siwaju si i, o ni oloogbe jẹ eni ti ki fifẹ ilu rẹ ṣere rara ti o si n ma fi gbogbo igba ja fun ijọba awarawa, ninu ọrọ rẹ, o sọ di mimọ pe gbogbo awọn tawọn wa ni Ipaja ni awọn yoo mọ ala iku rẹ nitori iṣẹ ti iya naa ṣe ninu aye awọn ara Ipaja ko kere rara. Olu...