Sanwó-Olú ṣèfilọ́lẹ̀ iṣẹ́ àkànṣe níjọba ìbílẹ̀ onídàgbàsókè Bàrígà



  Ọlaide Gold

Iṣẹ akanṣe rọrun lati ṣe fawọn alaga ijọba ibilẹ kaakiri ipinlẹ Eko nitoripe wọn n gba ipin owo wọn pẹlu irọrun, Gomina Babajide Sanw o-Olu  lo sọrọ yii lasiko to  ṣi iṣẹ akanṣe nijọba ibilẹ Bariga.

Yatọsi olu ileeṣẹ ijọba ibilẹ naa, gomina tun ṣi ojuna mọkanlelogun, ile ẹko alakọọbẹrẹ tuntun mẹta ati ojuko awọn oṣiṣe panapana, eyi ti Alaga ijọba ibilẹ onidagbasoke Bariga, Ọnarebu Kọlade Alabi, kọ fun igbayerọrun araalu.


Gomina sanwo-olu sọ pe "Awọn iṣẹ akanṣe wọnyi jẹ ẹtọ araalu atipe ojuṣe ijọba ni ẹtọ lati ṣeto fun ilu,".

Ó wa eọ alaga aṣẹṣẹyan iyen Arabinrin Bukọla Adedeji, lati ṣe aṣepari iṣẹ lori àwọn iṣẹ akanṣe yooku fun idagbasoke Bariga ati agbegbe rẹ wa lọ laisi ìmọ̀tara-ẹni-nìkan ki igba rẹ.

Níbi ayẹyẹ ọjọọ naa, ni Alabi tun ti kede pe wọn ti ṣe ayipada orúkọ Community Road sí Babajide Sanwo-Olu Road gẹ́gẹ́ bí ibọwọ fun gomina fun atilẹyin rẹ.
  
Àwọn alẹnulọrọ ninu oṣelu ti wọn wa nibi eto naa ni, alaga ẹgbẹ APC nipinlẹ Eko, Ẹni Ọwọ Cornelius Ọjẹlabi, àwọn igbimọ olugbmọran gomina, awọn aṣofin Eko, atawọn aṣaaju ẹgbẹ APC.



Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, 'Abiku' si ede Yoruba.