Lẹ́yìn tó ṣí ojúnà Abáranjẹ̀:Sanwo-Olú ṣèlérí látí ṣe ojúna Ìṣẹri-Ọ̀ṣun,Ikọtun
Ọlaide Gold
Awọn olugbe agbegbe Abaranjẹ, Igando-Ikọtun nijọba ibilẹ Alimọṣọ ko le gbagbe Ọjọru Wẹside, ọjọ keji oṣu keje ọdun yii bọrọ bi gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ati igbakeji rẹ, Dokita Ọbafẹmi Hamzat ṣe wa ṣi ojuna mọto ti wọn ṣẹṣẹ kọ pari ti wọn si kede pe o ti damulo.
Sanwo-Olu bẹrẹ irinajo naa ni opopona Dọpẹmu tẹlẹ nijọba ibilẹ Agege ti wọn ti yi orukọ rẹ pada si opopona Babajide Sanwo-Olu bayii.
Lẹyin naa lo darisi adugbo Abaranjẹ lagbegbe ijọba ibilẹ onidagbasoke Igando-Ikọtun labẹ agboorun ijoba ibilẹ Alimọṣọ.
Nigba to n sọrọ níbi ayẹyẹ naa, Sanwo-Olu ni kii ṣe igba akọkọ ree toun wa ṣefilọlẹ iṣẹ akanṣẹ lagbegbe naa. O ni, ṣiṣe ojuna Abaranjẹ mu igbaye irọrun ba awọn olugbe adugbo kọọkan to yii ka nitoripe lilọ bibọ ọkọ ti jẹ irọrun bayii.
Ni idahun si ẹbẹ awọn oriade lawọn agbegbe naa eyi ti wọn fi bẹbẹ fun afaara mọto nilu ikọtun, wọn ni nnkan to ma tun mu kí eto irinna rọrun lagbegbe naa siwaju si i niyẹn, ni gomina ba fun wọn lesi pe, ohun to rọrun fun ijọba lati ṣe ni ṣugbọn o yẹ ki wọn mọ bayii pe awọn ile tiwọn kọ sojuna mọto maa kuro nibẹ ki idagbasoke le wọlu.
O tun mu da wọn loju pe iṣakoso oun ṣi ma tẹsiwaju ninu ṣiṣe atunṣe awọn ojuna miiran lawọn agbegbe bii Ikọtun, Akẹsan, Ijagẹmọ, Ijẹdodo ati kikọ ojuna Iṣẹri-Ọṣun.
Opopona Abaranjẹ ti iwọn rẹ jẹ kilomita mẹta le mẹrindinlaadọrun, 3.86km lo so ọpọlọpọ agbegbe pọ nijọba ibilẹ Alimọṣọ, tawọn eeyan ro pe o ti bajẹ kọja atunṣe ni gomina Babajide Sanwo-Olu dawọle to si pari rẹ to si dẹẹrin pẹẹkẹ awọn olugbe agbegbe naa.
Onikọtun tilu Ikọtun, Ọba Azeez Gbadabiu Asiwaju, gboṣuba kare fun Gomina Sanwo-Olu fun awọn iṣẹ akanṣẹ to ṣe silu Ikọtun ati agbegbe rẹ. Oriade naa lawọn ojuna tawọn lero pe wọn ti bajẹ kọja atunṣe tawọn si n ro pe ko sijọba to ma fẹ dawọle e ni Sanwo-Olu ṣe ni aṣeyọri yii.
Kabiyesi wa rọ awọn araalu lati ri ojuna ọhun gẹgẹ bi ogun ibi wọn ki wọn le daabobo o, o ni, ki wọn ma gbero lati tu nnkan kan ta nibẹ nitoripe ẹni tọwọ ba tẹ
ma lọ faṣọ penpe roko ọba.
Lakotan, gomina wa fasiko naa rọ awọn olugbe agbegbe naa pé kí wọn jade lọjọ kejila oṣu yii lati dibo fun ẹgbẹ oṣelu APC ki idagbasoke le ma tẹsiwaju lawọn agbegbe wọn.
Comments
Post a Comment