Sanwó-Olú tún fìdí òmìnira ìjọba ìbílẹ̀ múlẹ̀, lásìkò tó ṣí iṣẹ́ àkànṣe tí Ọ̀ṣínọ́wọ̀ kọ́ sí Àgbòyí-Kétu
- Get link
- X
- Other Apps
Ọlaide Gold
Ẹṣẹ o gbero lọjọ Ẹti,Furaide to kọja,ṣeni ijọba ibilẹ onidagbasoke Agboyi-Ketu n rọ kẹkẹ, tawọn olugbe agbegbe naa si fidunnu wọn han bi Gomina Babajide Sanwo-Olu, ṣe ba wọn ṣiṣọ loju awọn iṣẹ akanṣe manigbagbe ti Ọnarebu Dele Ọṣinnọwọ ṣe.
Alaga naa, lati fi ẹmi ifọmọniyanṣe to ni sawọn araalu han lo mu ko ṣe aṣepari iṣẹ lori awọn iṣẹ akanṣe manigbagbe bii, Ọtunba Bushura Alebiosu Multipurpose Building, ile ekọ alakọọbẹrẹ Agboyi Community, Agboyi Ketu ICT Hub, Papa iṣere Ọba Taiwo Adeṣẹgun Lamina ati awọn opopona mi-in, fun anfaani araalu.
Gomina Sanwo-Olu, ninu ọrọ ẹ ṣapejuwe awọn iṣẹ akanṣe naa gẹgẹ bi atọna idagbasoke agbegbe, o ni awọn iṣẹ ti alaga naa ṣe wa ni ibamu pẹlu atẹ eto aato ilu ti iṣakoso oun gunle eyi ti yoo jẹ ọkọ idagbasoke fawọn eeyan agbegbe naa.
Sanwo-Olu tun fasiko naa dupẹ lọwọ awọn eeyan agbegbe naa bi wọn ṣe fi ibo wọn sọrọ lati yan ẹni ti yoo tukọ ijọba ibilẹ naa bayii, Ọnarebu Adetọla Abubakar, O ni, igbesẹ itẹsiwaju ni wọn gbe.
Ninu ọrọ tiẹ, Ọgbẹni Dele Ọṣinọwọ, lo ti sọ pe, awọn iṣẹ akanṣe naa jẹ ẹbun iranti fun awọn eniyan agbegbe naa ki wọn le ma ranti pe ẹnikan torukọ ẹ n jẹ Dele Ọṣinọwọ ṣe akoso ijọba ijọba ibilẹ Agboyi-Ketu pẹlu iwe iranti iṣẹ akanṣe manigbagbe to ṣe.
Ọṣinọwọ ni, aridaju si wa pe, ẹni to ṣẹṣẹ gba iṣakoso ijọba ibilẹ naa, Arabinrin Adetọla Abubakar, ma ṣe awọn iṣẹ idagbaoke to tun jọju siwaju si i.
O wa dupẹ lọwọ Gomina Babajide Sanwo-Olu, fun bo ṣe jẹ ejika ti ko jẹ kẹwu bọ fawọn ijọba ibilẹ Eko, o ni, ṣe ni gomina naa ma n kun awọn ijọba ibile lọwọ lasiko, eyi to jẹ ki wọn le ṣe awọn iṣẹ akanṣe aritọkasi ti ara fi n dẹ awọn araalu ilu kaakiri ipinlẹ naa.
Lakotan, Ọṣinọwọ dupẹ lọwọ araalu fun atilẹyin wọn ati ẹmi iṣọkan ti wọn fi ba oun lo ti gbogbo nnkan fi rọrun lasiko iṣakoso oun.
- Get link
- X
- Other Apps
Comments
Post a Comment