Nigba ti Iṣejọba ba kuna: Idaamu Ọgbara Ikorodu ati aibikita Ijọba ipinlẹ Eko: Asiwaju kii sa. Wiwa ojutu si wahala niṣẹ aṣiwaju rere - GRV
Ni ana, ajalu burúkú kan waye nilu Ikorodu latari omi ọ̀gbàrá nla to ya kaakiri ile, to si ba dukia jẹ, o tun fi ọpọlọpọ silẹ laini ibi aabo tabi ibùsùn.
Ajalu naa to yẹ ko gba idahun pajawiri lẹsẹkẹsẹ lọwọ Ijọba Ipinle Eko, oṣenilanu osi tun jẹ ohun iyalẹnu nigba ti kọmisọna ipinlẹ Eko fun eto ayika ati awọn orisun omi gba awọn olugbe agbegbe tọrọ naa kan lamọran pe ki wọn kuro ni agbegbe naa.
Idahun ti kọmisọna fii yii kii ṣe ti ibanilọkan jẹ nikan, o tun ṣe afihan iru iṣakoso ìjọba ipinlẹ Eko, iṣakoso to ni aibikita si iya ti awọn eyan doju kọ.
Eyi kii ṣe ajalu adayeba, o jẹ afihan kudiẹkudiẹ iṣejọba labẹ ẹgbẹ oṣelu APC ti n dari ipinle Eko.
Ibere to wa nilẹ bayii ni pe, ní gbati kọmisọna ni ki awọn eyan fi ile wọn silẹ, ibọ ni ki wọn lọ? Ṣé wọn pese afin ọba fun wọn ni, abi agbala awọn oloye abi ọgbà awọn ọlọpa ni wọn ni ki wọn ma lọ.
Ko sibi meji ti wọn yoo lọ ju oju popona lọ, wọn yoo wa ma wọ sun kiri, abi nibo ni ki ẹni ti ko nile lori ma lọ.
Iṣoro ọgbara nilu Ikorodu kii ṣe ohun tuntun, igba gbogbo ni awọn olugbe ibẹ ma n ṣe aroye ti awọn onimọ nípa ayika naa si n ṣe ikilọ.
Ọpọlọpọ atunṣe to jẹ ọna abayọ ni awọn amoye ti la kalẹ fun ìjọba sugbọn ko si eyi ti wọn mulo ninu rẹ.
Gbogbo koto ida ominu lo ti di pa ti rogbodiyan omi yale agbára ya shọbu ko si ni ojutu lọdọdun.
Awọn ohun to yẹ kí jọba ṣe
Asiko ti to fun ijọba ipinlẹ Eko ati ẹgbẹ oṣelu APC lati ji si ojuse wọn,idagbasoke kii ṣe nipa awọn afara ati awọn ọkọ ofurufu nikan; bi ki ṣe nipa awọn eniyan, obinrin ti o padanu ile itaja rẹ sinu ọ̀gbàrá, kini ko ṣe, awọn ọmọde ti o sun lori ilẹ tutu nkọ, awọn idile ti ko si ibi ti wọn yoo sun nkọ?
Ti ijọba ko ba leri ojutu si rogbodiyan naa, awọn ọmọ ipinlẹ Eko lero pe o yẹ ki wọn lanu àwọn eyan loju ki se ki kọmisọna wa ni ki awọn eyan fi ile wọn silẹ lai pese ibi ti wọn yoo ma gbe.
Awọn ohun ti o yẹ ki ìjọba ṣe
1. Ojutu ni kiakia ati awọn ibugbe ti aralu le gbe fungba diẹ
Ijọba ipinlẹ Eko le fi awọn ileewe ijọba ṣe eto ile ni kíákíá fún àwon eyan ki wọn gbe fun igba diẹ naa, wọn tun le lo awọn gbọgan nla fun wọn.
Ijọba ni lati pese ounje, omi mimọ, itọju ilera, ati ibusun fun awọn eniyan tọrọ kan.
2. ijọba ni lati ṣe agbeyẹwo gbogbo agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹ:
Wọn ni lati ran awọn ajọ eleto pajawiri si awọn agbegbe ti ìṣẹ̀lẹ̀ naa ti ṣẹ, ki wọn si ṣe koto idaminu si awọn ibi to nilo rẹ bakanna ni ki wọn ko gbogbo koto idaminu to ba ti di pa.
3. Atilẹyin Pẹlu Owo
Ijọba nilo ati pese owo tabi owo san diẹdiẹ ti ko ni ele lori fun gbogbo awọn ti ọrọ naa kan.
Ijọba ipinlẹ Eko ko gbọdọ da awọn eyan naa da bukata wọn, olori gbọdọ ran aralu lọwọ ni, wọn ko tun gbọdọ ma ṣe ikede ti yoo bawọn lọkan jẹ ju boti wa lọ.
Thomas Hobbes ṣe ikilo nipa awujọ ti ko ni adehun awujọ, nibiti ijọba ti kuna lati daabobo awọn eniyan rẹ.
Ikilọ yẹn kii ṣe amọran mọ, o ti n ṣẹlẹ ni awọn agbegbe wa.
Ẹ jẹ ko di mimọ fun iṣakoso ìjọba ipinlẹ Eko labẹ asia ẹgbẹ oselu APC pe :
Asaju ki sa, ojutu si rogbodiyan ni asaju rere ma n wa ni gba gbogbo.
Ẹ jẹ ki atẹgun alafia fẹ si awọn mẹkunnu
Ipinlẹ Eko nilo ohun to dara
Ikorodu nilo amojuto to ye koro
Awọn eniyan ibẹ nilo olori toun ṣíṣẹ fun wọn ki ṣe eyi toun ṣíṣẹ tako wọn
Comments
Post a Comment