Àwọn ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìtọpinpin àwọn tí wọ́n jí èrò ọkọ̀ akérò gbé lọ ni Benue






 Ọlaide Gold


Ileeṣẹ ọlọpaa ti orileede Naijiria ti gbera tan o, wọn ti ji giri bayii koda wọn ni iṣẹ ti yatọ latari ara ọtọ tiwọn fi n tọpinpin awọn ajinnigbe lọwọlọwọ.

Irinṣẹ ayaworan o n fo loke taa mọ si 'Drone Camera' ni wọn ko sita bayii ti wọn fi n ṣe akasilẹ ibuba awọn ajinnigbe, wọn n lepa awọn oniṣẹẹbi naa bakan naa ni wọn tun n doola gbogbo awọn tiwọn wa nigbekun kuro lọwọ wọn.

Laipẹ yii ni wọn ni ọkọ akero ijọba kan ti wọn pe ni 'Benue Links' fẹẹ gba ojuna Otukpo lọ si Otukpa nijọba ibilẹ Okpokwu lati lọ fori sọ marosẹ Makurdi ṣugbọn tawọn ẹṣin o koku bọ sita lojuna naa laago mẹfa irọlẹ lọjọ Sannde tiwọn si kọ lu wọn.

Wọn ni, ṣe ni wọn gbe ibọn gbakan rọrun kọrun ti ko si sẹni to le sọ pe eyi taa wi fun ọgbọ ni ọgbọ n gbọ titi ti wọn fi gba owo ati gbogbo dukia wọn ṣugbọn o jọ bi ẹnipe owo tiwọn ri gba ko ka iye owo ọta ibọn ti wọn ra lo jẹ ki wọn ko ero mọkanla tọkọ naa ko pẹlu awakọ wọn to ṣe ikejila wọnu igbo lọ.

Wọn ni iporuuru ọkan deba awọn eeyan agbegbe tiṣẹlẹ naa ti waye iyẹn lo mu kawọn ọlọpaa tete bẹrẹ iṣẹ, wọn da ẹrọ ẹyẹba sita, wọn ni ojuko ibi ti wọn gbe awọn eeyan naa gba ninu igbo lawọn ẹrọ ayaworan naa ṣe bagẹbagẹ gba tiwọn si n ka ibuba awọn araabi  silẹ.

Ni bayii, ileeṣẹ ọlọpaa ti ni kawọn mọlẹbi awọn tiwọn jigbe salọ naa lọ fọkan balẹ nitoripe gbogbo iroyin ti awọn ẹrọ naa ka silẹ yoo mu kiṣẹ awọn rọrun atipe aṣiiri oriṣiriṣi tun ti hande ninu awọn akasilẹ naa.

Bo tiẹ jẹ pe kọmiṣanna ọlọpaa nipinle Benue, ti ni, ko si ọlọpaa to gbọdọ sun titi tawọn maa fi da awọn mejila naa pada sọdọ awọn mọlẹbi wọn ṣugbọn awọn mọlẹbi awọn eeyan rawọ ẹbẹ si gomina Benue,wọn ni bi ẹrọ ayaworan awọn ọlọpaa ba ka iroyin silẹ loootọ ko yẹ ki wọn tun maa dajọ si i.
                              

Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, 'Abiku' si ede Yoruba.