Sanwó-Olú ṣèlérí ètò ìrànlọ́wọ́ láti sàmì àyájọ́ àwọn obìnrin lágbàáyé


Ọlaide Gold

Ipa tawọn obinrin n ko ninu idagbasoke orileede ko kere, o to ki wọn ri iranlọwọ gba lọwọ ijọba lati le jẹ anfaani dẹmọnkiresi siwaju si i.


Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu lo sọrọ yii lọjọ Ẹti Furaide nibi ayẹyẹ ayajọ awọn obinrin lagbaaye eyi to waye ninu papa iṣere Onikan nilu Eko.

Sanwo-Olu, fidi ẹ mulẹ pe,  ipa ti obinrin n ko ninu idagbasoke agbegbe wọn ati orileede lapapọ ko kere rara bakan naa lo ni igbesẹ lati ṣeranwọ fawọn obinrin naa wa ni ibamu pẹlu eto igbayerọrun ti ijọba Eko gunle.

Oludanilẹkọọ ọjọ naa, to wa lati ẹka ẹkọ to n mojuto iṣedeede ọpọlọ ni fasiti imọ iṣegun ipinlẹ Eko,  Ọjọgbọn Olurotimi Coker ṣalaye pe, oriṣiriṣi iṣẹ ile tawọn obinrin ma n ṣe laarin wakati kan le ṣakoba fun iṣe deede ọpọlọ wọn, o ni, awọn obinrin o yẹ ki wọn tun ma gbe nnkan sọkan lẹyin lọta, fọṣọ,sebẹ ati itọju ọmọ. Olurotimi ni ṣeni ki wọn ma sọ ẹdun ọkan wọn jade ki ọkan le fuyẹ.
O ni ki wọn maa ṣamulo awọn nnkan marun to ma n mu ki ọkan fuyẹ bii ijo jijo,ẹrin , ṣiṣe akọsilẹ ẹdun ọkan wọn sinu iwe pelebe, ere idaraya ati ibaṣepọ awujọ.
 
Abilekọ Bọlaji Dada, Kọmiṣanna to n ri  sọrọ awọn obinrin nipinlẹ Eko, gboṣuba kare fun iṣakoso Gomina Babajide Sanwo-Olu fun irolagbara to ṣe fawọn obinrin eyi to n mu wọn ṣe daadaa ninu ọrọ aje wọn.
 
Awọn obinrin naa yan bi ologun kọja niwaju gomina , Lati ijọba ibilẹ ogun ati ijọba ibilẹ onidagbasoke mẹtadinlogoji to wa nipinlẹ Eko lawọn aṣoju ti wa, gbogbo wọn ni gomina fun ni ẹbun adogan idana igbalode lọ sile.


Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa