Oluwaloni ṣedaro alaga kansu to ku lojiji l'Ekoo



Inu ipayinkeke ati ibanujẹ ọkan ni gbogbo ara agbegbe Ayobo-Ipaja Local Council Development Area (LCDA) wa, latari iku alaga kẹta to jẹ ni agbegbe naa, Hon. Chief (Mrs.) Bolatito Shobowale.

 

Ẹni to jẹ adele alaga Ayobo-Ipaja LCDA, Otunba Ladi Oluwaloni (OLO 1), lọ sọrọ naa di mimọ, pẹlu ibanujẹ ọkan ni Oluwaloni fi kede iku oloogbe Shobowale ni ọjọ Ẹti ọsẹ yii.

 

O ni, iku arabinrin naa jẹ kayeefi fun awọn ati pe iṣẹlẹ to bani lọkan jẹ gidi ni iku naa jẹ,nitori oloogbe jẹ ẹni to da ni awujọ awọn.

 

Oluwaloni ṣe apejuwe Shobowale gẹgẹ bi eniyan rere to fẹ ilọsiwaju ilu, o ni oloogbe naa ki i ṣe olori nikan, o ni o jẹ alatilẹyin rere, igi lẹyin ọgba ọpọlọpọ awọn eeyan lo tun jẹ pẹlu.

 

Siwaju si i,  o ni oloogbe jẹ eni ti ki fifẹ ilu rẹ ṣere rara ti o si n ma fi gbogbo igba ja fun ijọba awarawa, ninu ọrọ rẹ, o sọ di mimọ pe gbogbo awọn tawọn wa ni Ipaja ni awọn yoo mọ ala iku rẹ nitori iṣẹ ti iya naa ṣe ninu aye awọn ara Ipaja ko kere rara.

 

Oluwaloni jẹ ko tun di mimọ pe ọpọlọpọ idagbasoke towaye ninu Ipaja lo ti ọwọ Shobowale wa, ni akoko rẹ.

 

O ni ipinlẹ rere ni Shobowale fi lelẹ ni Ipaja, ẹsẹ naa ni awọn si n tọ yi, o ni ni akoko to wa lori oye, o ṣe awọn atunṣe aritọkasi.

  
 
O ki awọn ọmọ, ẹbi, ara ati ọrẹ ku arafẹraku ẹni re to lọ, o wa gba a ladura pe ki Ọlọrun rọ wọn loju, ko si tẹ oloogbe naa si afẹfẹ rere.

 

 

Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Sanwó-Olú ṣèlérí ètò ìrànlọ́wọ́ láti sàmì àyájọ́ àwọn obìnrin lágbàáyé