Ó ṣeéṣe kí ìpínlẹ́ Èkó má yáwó ṣiṣẹ́ àkànṣe-Ọpẹ́ George
Ọlaide Gold
Ninu ọrọ ikinni kaabọ sibi ipade naa to waye pẹlu awọn oniroyin ni Alausa n'Ikẹja ni kọmiṣanna iroyin, Ọgbẹni Gbenga Ọmọtọṣọ ti ṣalaye pe ipade naa dabi oriṣa teeyan n bọ lọdọọun ni toripe ni kete ti gomina ba ti gba ibọwọlu owo iṣuna lo ma n pe iru ipade bẹẹ lati ṣalaye bi wọn ṣe fẹ nawo fawọn araalu kawọn eeyan le mọ nnkan tiwọn n fowo wọn ṣe.
Ọpẹ George, kọmiṣanna fun ọrọ aato ilu ati iṣuna ni ipinlẹ Eko ni iṣuna tiye rẹ ni tiriliọnu mẹta naira ni gomina gbe siwaju awọn aṣofin Eko tiwọn si ti bọwọlu u. O ni, afojusun ijọba ninu eto iṣuna naa ni lati ri dajupe awọn araalu jẹ anfaani ijọba awaarawa.
Ọkunrin naa ni, kaakiri ẹkun idibo maraarun nipinlẹ Eko, iyẹn Ikẹja, Badagry, Ikorodu, Ẹpẹ, Erekuṣu Eko ati Agege nijọba yoo tun ṣiṣẹ de tawọn eeyan agbegbe naa si maa ṣe akọsilẹ awọn iṣẹ akanṣe aritọkasi.
Bakan naa lo sọ pe, ijọba ti ṣetan lati pari iṣẹ lori agba omi to wa nilu Adiyan.
O tun sọ pe, o ṣee ṣe kijọba Eko ma ya owo kankan, o ni owo tijọba pa labẹle naa to lati ṣakojọ tiriliọnu mẹta le ni ọtalelọọdunrun din mẹta naira tiwọn la
kalẹ fun eto iṣuna tọdun yii.
Comments
Post a Comment