Ìlera Èkó: àwọn elétò ìlèra sọ nípà ètò tuntun fáwọn aráàlú


Ọlaide Gold
  
Erongba ijọba Eko ni lati ṣeto ilera pipe fawọn araalu atipe wọn ti n gbiyanju ko le jẹ itẹwọgba fun gbogbo eeyan fun igbayerọrun wọn.

Akọwe Agba lẹka eto ilera Eko, Dokita Emmanuella Zamba lo sọrọ naa lonii ni ọfiisi ilera Eko n'Ikẹja lasiko ipade to waye pẹlu awọn oniroyin  

Nibẹ lo ti ṣalaye pe, ẹka to n mojuto eto ilera Eko ti sa ipa wọn lati ri dajupe ilera pipe tẹ araalu lọwọ nitoripe bawọn eeyan ilu b n ṣojojo ko le si nnkan to n jẹ ilọsiwaju.

Oriṣiiriṣii eto nijọba ipinlẹ Eko ti la kalẹ lẹka ilera tawọn eeyan si ti n jẹ anfaani rẹ tiwọn si  n dupẹ ṣugbọn iroyin naa  ko tii tan kalẹ to nitori naa lo ṣe ṣe pataki fawọn oniroyin lati tunbọ tan iroyin naa ka lori awọn atẹ iroyin wọn ko le fọnka sigboro ko si jẹ itẹwọgba paapaa julọ laarin awọn mẹkunnu.

Abilekọ Tayọ Adetoro ṣalayé bi eto naa ṣe rọrun to lati ṣe fawọn mẹkunnu pẹlu owo pẹntọ. O mẹnuba bi ẹka ilera naa ṣe n gbawọn eeyan tiwọn n gbe nipinlẹ Ogun ṣugbọn tiwọn n ṣiṣẹ nipinlẹ Eko laaaye lati jẹ anfaani ilera Eko pẹlu ajọṣepọ OGSA.
                       
Bẹo ba gbagbe, ninu oṣu keje ọdun yii ni gomina Eko, Babajide Sanwo-Olu paṣẹ fawọn oniṣẹ ọwọ atawọn ileeṣẹ nlanla ati ileeṣẹ aladani pe ki wọn fi awọn    oṣiṣẹ wọn sabẹ ilera eko fun igbayerọrun wọn.

Awọn eeyan ipinlẹ Eko ni anfaani lati forukọ silẹ fun eto ilera yii biwọn ba ti ni kaadi igbeluu iyẹn LASSARA. Ilera Eko duro gẹgẹ bi itura lati jẹ igbadun ilera lowo pọọku 

O ti le lẹgbẹrun kan eeyan ti wọn ti wa lori eto ilera eko tawọn eeyan si n jẹrii loriṣiiriṣii lori anfaani ayẹwo ọfẹẹ tawọn ileewosan tiwọn 

Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Sanwó-Olú ṣèlérí ètò ìrànlọ́wọ́ láti sàmì àyájọ́ àwọn obìnrin lágbàáyé