Gomina Sanwo-Olu fawọn akẹkọọ ileewe ẹkọṣẹ ọwọ lẹbun lasiko ayẹyẹ ikẹkọọjade wọn


Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu nibi ayẹyẹ ikẹkọọjade awọn akẹkọọ gboye ileewe girama ẹkọṣẹ iyẹn Tẹkiniika ti ipinlẹ naa to waye ninu gbọngan "blueroof" lọgba ileeṣẹ tẹlifisan Eko lọjọ keji oṣu kejila niluu Ikẹja l'Ekoo lo fi ifarahan rẹ ṣe koriya fun wọn.

Awọn akẹkọọ to le lẹgbẹrun meji ni wọn kọṣẹ yege, ti wọn si kẹkọọ gbọye l'awọn ile iwe sẹkọndiri Tẹkiniika mẹrẹẹrin to wa niluu Eko, nibẹ lawọn akẹkọọ kan si gbami ẹyẹ fifakọyọ ati pipegede ju awọn akẹgbẹ wọn yooku lọ.

Awọn akẹkọọ to gbami ẹyẹ ẹni to peregede julọ ni, ẹni akọọkọ; Uchendu David lati ẹka ileewe ẹkọṣẹ ọwọ ti Ikọtun, ẹni keji, Daniel Salami, lati Agidingbi, ẹni kẹta, Benedict Wisdom, lati ẹka Ado-Soba, ẹni kẹrin, Adedeji Oluwapẹlumi J, Agidingbi, Boyejọ Joseph Babatunde, Ẹpẹ, Ọdọfin Moyọsọrẹ, Ikorodu, Arebisọla Grace, Ikọtun, Abalogu Mary Ifeoma, Ikọtun, Okpako Irughene Daniella, Ikọtun ati Ibiwọye Ẹniọla Modupẹ lati ileewe Tẹkiniika sẹkọndiri Agidingbi ni Ipinlẹ Eko.

Ṣaaju kí Gomina Sanwo-Olu to sọrọ pataki to ni fun awọn akẹkọọ naa ipinlẹ ni adari ileewe ẹkọṣẹ ọwọ to wa niluu Ẹpẹ l'Ekoo, iyẹn Ọjọgbọn Wọle Adefowokẹ ṣafihan awọn akẹkọọ gboye naa fun gomina.

Ninu ọrọ igbani-niyanju rẹ si awọn akẹkọọ ọun ni gomina Babajide ti ṣapejuwe wọn gẹgẹ bi aṣẹgun, to si sọ pe, pẹlu awọn ohun eelo amayedẹrun igbalode ti awọn ti pese si awọn ile-ẹkọ wọn kaakiri lati se wọn jìna ti wọn fi ṣaṣeyọri, o ni idaniloju wa pe, ọjọ ọla rere wa fun wọn. Gomina tun wa gba awọn akẹkọọ to si wa labẹ ẹkọ lọwọ yii nimọran pe, ki wọn gbajumọ ẹkọ wọn daadaa kí aṣeyọri tiwọn le tun dara ju ti awọn ti isaju lọ.

Nibi ayẹyẹ aṣekagba awọn akẹkọọ gboye yii ni awọn obi, alagbatọ ati awọn leekan-leekan eeyan awujọ tu jade wa, lati ba awọn ọmọ oloriire naa yayọ aṣeyọri wọn.

Lara awọn eeyan pataki to ifarahan wọn ṣe koriya fun awọn akẹkọọ gboye naa ni Ọlọla julọ ipinlẹ Eko, Gomina Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu, igbakeji rẹ, Dokita Kadri Ọbafẹmi Hamzat, Kọmisan-na fun ile-ẹkọ girama ipinlẹ Eko, Ọnọrebu Jamiu Tọlani Alli-Balogun, Arabinrin Moronke Azeez, akọwe agba ajọ to n ri si iṣẹ akanṣe ati ileewe sẹkọndiri Tẹkiniika ipinlẹ Eko (LAGOS STATE TECHNICAL AND VOCATIONAL EDUCATION BOARD) "LASTVEB", Ọnọrebu Mosunmọla Rotimi Sangodara, awọn oludamọran agba fun gomina l'awọn ẹka ijọba ipinlẹ Eko ati awọn ọtọnkulu miiran.

Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Sanwó-Olú ṣèlérí ètò ìrànlọ́wọ́ láti sàmì àyájọ́ àwọn obìnrin lágbàáyé