Ẹ̀bùn òpin ọdún:Sanwó-Olú ṣèrànwọ́ fáwọ́n oníṣẹ́ ọwọ́ l'Ekoo
Ọlaide Gold
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ti sọpe oun ko ni yee ran araalu lọwọ nipa pipese awọn ohun amayedẹrun ati ṣiṣeranwọ fawọn ọmọ ẹkọṣẹ atawọn oniṣowo.
O sọrọ naa lọjọru Wẹside, nibi ayẹyẹ ikẹkọọjade awọn oniṣẹ ọwọ tiwọn ṣetan labẹ ikẹkọọ ẹka ileeṣẹ to n ri sọrọ awọn awọn obinrin ati ironilgbara nipinlẹ Eko iyẹn Ministry of Women Affairs and Poverty Alleviation (WAPA) to waye ni Agidingbi, Ikeja.
Ẹgbẹrun kan aabọ (1500) awọn tiwọn kọṣẹ yege naa niwọn gba ẹbun irinṣẹ ọfẹẹ bii maṣiini iranṣọ ati ẹyi to n lẹ okuta didan mọ aṣọ, ẹrọ ilọta, irinṣẹ yadirẹsa ati tawọn gẹrungẹrun, irinṣẹ awọn ketira, irinṣẹ wẹda ati eyi tiwọn fi nlẹ taili, iranlọwọ fawọn eleto ọgbin ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Igbakeji gomina Eko, Dokita Ọbafẹmi Hamzat nigba to gbẹnu gomina Sanwo-Olu sọrọ nibi eto ikẹkọọjade naa sọpe ijọba n gbiyanju lati sọludẹrọ nipa ṣiṣeranwọ fawọn araalu. O ni itẹsiwaju ma deba ipinle naa bawọn araalu ba niṣẹ lọwọ.
Idunnu ijọba Eko ni bawọn araalu paapaa julọ, awọn ọdọ ṣe n jẹrii si abajade iranwọ tijọba ṣe funwọn. Hamzat ni igbesẹ tijọba gunle naa wa ni ibamu pẹlu fifun awọn eeyan lọjọ ọla to dara.
Gomina wa rọ awọn tiwọn jẹ anfaani iranwọ ẹbun owo iṣẹ naa pe ki wọn lo owo naa fun okoowo wọn ki wọn maṣe ko o lori aṣọ ẹbi tabi nnkan tiko wulo.
Gẹgẹ bi ọrọ, Abilekọ Bọlaji Cecilia Dada, Kọmiṣanna to n ri sọrọ awọn obinrin ati eto irolagbara l'Ekoo. O ni ,gomina Sanwo-Olu tun jọ araalu loju lopin ọdun yii bọ ṣe ṣeto irolagbara funwọn nipa fifunwọn ni irinṣẹ tawọn oniṣowo kan si gba ẹbun owo.
Awọn oniṣowo kaakiri aarin ọja ni gomina ṣajọ laifi tẹya tabi ẹsin ṣe, to si funwọn lẹbun owo idokowo gẹgẹ bi iranwọ
Lọdun yii nikan, gomina ti ran ida aadọrin eeyan lọwọ fun itẹsiwaju iṣẹ ati okoowo wọn.
Obinrin naa wa gba awọn tiwọn jẹ anfaani iranwọ naa nimọran pe kiwọn lo o fun itẹsiwaju rere bẹẹni wọn o gbọdọ ta a danu ni gbanjo.
Comments
Post a Comment