Sanwó-Olú sọ owó àwọ́n oníṣẹ́ ọwọ́ di mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dógùn náírà,ó tún ṣèrànwọ́ irinṣẹ́ rẹpẹtẹ



  Ọlaide Gold


Ṣẹnkẹn  ninu awọn oniṣẹ ọwọ dun lọjọ Tuside latari iroyin ayọ tiwọn gbọ latẹnu gomina Eko, Ọgbẹni Babajide Sanwo-Olu pe afikun ma deba owo wọn pẹlu miliọnu mẹsan naira. Owo naa ni gomina fẹẹ fi kun miliọnu mẹfa naira tijọba n san tẹlẹ,eyiti apapọ rẹ wa jẹ miliọnu mẹẹẹdogun naira bayii.

Sanwo-Olu ṣeleri  naa nibi ayẹyẹ ikẹkọọjade ti wọn ṣe fawọn oniṣẹ ọwọ to wa nipinlẹ Ekoo lẹka ẹgbẹ awọn oniṣẹ ọwọ ati oniṣowo iyẹn Lagos State Council of Tradesmen and Artisans, LASCOTA.


 Nibẹ ni kọmiṣanna fun eto idaṣẹsilẹ ati ironilagbara, Ọgbẹni Akinyẹmi Ajigbọtafẹ ti gboriyin fun Gomina Babajide Sanwo-olu fun agbekalẹ awọn eto igbaye irọrun fun araalu to n ṣe ni gbogbo igba. O ni,riro awọn oniṣẹ ọwọ lagbara maa le iṣẹ wọgbẹ lawujọ

      

Ayẹyẹ naa to waye ninu gbọngan Blue Roof l'ọgba redio ipinlẹ naa ni Agidingbi, Ikeja, l’Ekoo, ni wọn ti bura ikẹkọọjade fun awọn akẹkọọ ẹgbẹfa tiwọn ṣẹṣẹ kọṣẹ yege lẹyin oṣu mẹjọ, tijọba si funwọn nirinṣẹ tuntun gẹgẹ bi irolagbara.

Gomina Sanwo-Olu nigba to sọrọ nibi ayẹyẹ naa ni, inu mi dun gan an ni, mo ni igbagbo pe, awọn eto ironilagbara ta n ṣe lo n fun awọn araalu ni ireti isọdọtun ti Aarẹ Tinubu n tẹnumọ.

Sanwo-Olu ni,ẹkọ o pin sibikan nitori naa kawọn akẹkọọjade naa maa ṣamulo imọ ẹrọ lati mu ọtun ba iṣẹ wọn siwaju sii. O gba awọn Olokoowo nimọran pe ki wọn 

dẹkun lati maa ko owo okoowo wọn lọ sileejọsin toripe bi wọn ba lo o botiyẹ awọn naa ma ni itẹsiwaju. 

Sanwo-Olu ni, awọn oniṣẹ ọwọ lo laye ṣugbọn pupọ ninu wọn ni ko mọ iyi nnkan tiwọn gbe lọwọ bakan naa lo ki awọn akẹkọọjade naa nilọ pe ki wọn maṣe lu irinṣẹ tijọba fun wọn ta ni gbanjo.


Lakotan, gomina ni, ijọba Eko ti ni adehun pẹlu awọn ileefowopamọ kan lati ṣeto ẹyawo fawọn oniṣẹ ọwọ lọna irọrun ti sisan pada rẹ ko ni mu inira lọwọ.

 


 

Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, 'Abiku' si ede Yoruba.