Sanwó-Olú búra fún alága tuntun n'Ijọba ìbílẹ̀ Onígbòngbò


Ọlaide Gold

Ọjọ Mọnde, ọjọ kọkanla oṣu yii ni gomina Babajide Sanwo-Olu bura wọle fun, Agbẹjọro Rekiyah Olufunkẹ Hassan gẹgẹ bi alaga tuntun fun ijọba ibilẹ Onidagbasoke Onigbongbo . 

Laipẹ yii ni ijọba Eko kede ipapoda alaga ijọba ibilẹ naa tẹlẹ,Ọnarebu Ọladọtun Ọlakunle ẹni tiwọn bura wọle fun gẹgẹ bi alaga lẹyinti ọga tiẹ naa jade laye.

Lasiko to ṣebura fun alaga tuntun naa, Gomina Sanwo-Olu ni, o ṣeni laanu pe ijọba ibilẹ Onigbongbo padanu alaga meji leralera ṣugbọn iṣe gbọdọ tẹsiwaju,idi niyẹn ti igbakeji rẹ gbọdọ bọ sipo alaga gẹgẹ bi alakalẹ ofin iṣakoso ijọba ibilẹ ori kẹrindinlọgbọn, ipin kin-in-in, ọdun 2015.

Sanwo-Olu ni, loootọ ni iku alaga ana dunni jọjọ ṣugbọn ipo alaga ko gbọdọ ṣofo gẹgẹ bi alakalẹ ofin. O wa rọ gbogbo awọn eeyan ijọba ibilẹ naa ki wọn ma gbadura ẹmi gigun fun alaga wọn tuntun.

Ninu ọrọ idupẹ tiẹ,alaga tuntun naa dupẹ lọwọ gomina ati igbimọ iṣejọba rẹ fun apẹẹrẹ aṣiwaju rere bakan naa lo rọ awọn eeyan pe ki wọn dide iṣẹju kan laifọhun lati bu ọla fun ọga rẹ to jade laye.

Alaga tuntun naa ṣeleri lati bẹrẹ nibiti oloogbe naa ba iṣẹ de atipe oun maa ṣe awọn iṣẹ akanṣe aritọkasi fun itẹsiwaju ijọba ibilẹ naa leyi ti yoo jẹ moriya fun ẹgbẹ oṣelu APC lapapọ.

Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, 'Abiku' si ede Yoruba.