Ìjọba Èkó máa ti àwọn gáráàjì kan pa-Ọṣiyẹmi



Ọlaide Gold

Ijọba Eko ti bẹrẹ sii fagile gbogbo garaaji ọkọ awuruju tiwọn n gbero idalẹ nibi tijọba o fọwọsi.
Kọmiṣanna fun lilọ bibọ ọkọ nipinlẹ naa, Ọgbẹni Ṣeun Oṣiyẹmi, lo fọrọ naa lede lasiko to ṣepade pẹlu awọn oniroyin lọjọ Furaide ni Alahusa. O ni, garaaji tijọba ba fọwọsi nikan lawọn eeyan ti le wọkọ 
.            
Ọṣiyẹmi ni, ẹka ileeṣẹ ijọba Eko to n risi  lilọ bibọ ọkọ n ṣiṣẹ takuntakun lati ri pe  ẹmi awọn ero to n wọkọ ko bọ sọwọ awọn agbenipa.

Ni bayii, akọsilẹ awọn ero tiwọn wa ninu ọkọ to fẹ gbera lọsi idalẹ gbọdọ wa pẹlu ijọba bakan naa ni ko nii saaye garaaji ọkọ awuruju nitoripe gbogbo ibudokọ ero gbọdọ forukọsilẹ lọdọ ijọba. 

"Ajọṣepọ to dan mọran ti wa laarin ẹgbẹ onimọto iyẹn Lagos State Parks and Gardens pẹlu ijọba Eko,wọn si ti ṣetan lati mu iyatọ ba eto irinna nipa ṣiṣe amulo imọ erọ tiwọn maa fi gba orukọ awọn ero silẹ."

Kọmiṣanna naa ṣalaye siwaju si i pe, awọn akọṣẹmọṣẹ onimọ ẹrọ niwọn ma  ran awọn awakọ lọwọ lati gba orukọ awọn ero sinu ẹrọ kọmputa. O ni, bi ijọba Eko ṣe ṣaṣeyọri lori kaadi iwọkọ alawọ bulu 'Cowry card' naa ni akọsilẹ naa ma fẹsẹmulẹ.
 Ọkunrin naa ni, o ṣe pataki fun ijọba lati mọ iye eeyan to n wọle ati eeyan to n jade nipinlẹ naa lojoojumọ.
Ni idahun si boya awọn ajinigbe ma bẹrẹ si i pe awọn eeyan tiwọn ba gba orukọ wọn silẹ ni garaaji, kọmiṣanna naa ni ko si nnkan to jọ bẹẹ pẹlu awọn akọṣẹmọṣẹ tijọba yan lati ṣiṣẹ naa toripe, ko seni to pe ẹnikẹni ni pajawiri latigba tiwọn ti forukọ silẹ gẹgẹ bii olugbe Eko.
Ọgbẹni Usman Teslim, akọwe agba fun ẹgbẹ onimọto l'Ekoo ninu ọrọ tiẹ sọ pe, bo tiẹ jẹ pe akọsilẹ awọn ero ti wa tẹlẹ lawọn ibudokọ tawọn maa n gba orukọ awọn ero silẹ ṣugbọn o dara bi ijọba tun ṣe fẹ sọ ọ di ti onimọ ẹrọ.
O ni, ipa tawọn ọlọkọ ero n ko ninu ọrọ aje ipinlẹ naa ko kere latari owo to n wọle sapo ijọba lati awọn ibudokọ tijọba fọwọsi ṣugbọn atunṣe tijọba mu wọle nipa imọ ẹrọ ma tun mu ki nnkan rọrun lawọn ibudokọ kaakiri ipinlẹ Eko.

Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, 'Abiku' si ede Yoruba.