Sanwó-Olú ní, àwọn aráàlú ti lè ṣàmúlò ibùdó àṣà J.Randle
Ọlaide Gold
Lonii ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹwaa, ọdun 2024 ni gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu fitan tuntun balẹ bo ṣe kede amulo gbọngan aṣa to wa nilu Onikan fáwọn aráàlú iyẹn J.Randle Center for Yoruba History.
Sanwo-Olu ni, ṣaaju kawọn oyinbo amunisin to de nilu EKo ti jẹ ibudo aṣa bakan naa ni aṣa ti bẹrẹ lati ede ta n sọ jade lẹnu ṣugbọn awọn oyinbo niwọn sọ ede wa di ede ara oko tiwọn si fonte le e pe, ijiya wa fun ọmọ to ba sọ ede rẹ koda owo ounjẹ rẹ lo ma fi ṣan owo itanran.
Gẹgẹ bi ọrọ gomina, awọn oyinbo ṣe oriṣiiriṣii ibi igbafẹ funra
wọn nilu Ekoo ,bii tennis club, ibiti wọn ti n fẹṣin sare tiwọn pe ni race corse atawọn ibi igbafẹ mi-in tawọn alawọ funfun fẹran ṣugbọn itan ti yipada bayii nitori ayika wa ti sọ pupọ nipa aṣa wa, awa naa ti ni Yoruba tenis club, ile iṣura aṣa ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Sanwo-Olu ni, ṣeni a jogun aṣa ati iṣe lọwọ awọn baba nla wa ṣugbọn awọn ọdọ iwoyii gbọdọ mọ ipa pataki ti aṣa, iṣe ati irinajo afẹ nko ninu ọrọ aje orileede.
Loootọ, lawọn kan ti ji awọn nnkan iṣẹmbaye wa lọ soke okun ṣugbọn ohun taa nilo ni lati ṣedapada aṣa ati iṣe ilẹẹwa.
komiṣanna fọrọ irinajo afẹ, Abilekọ Tokẹ Benson-Awoyinka, ninu ọrọ tiẹ ni, ibudo aṣa naa wa fun lati ṣe igbelarugẹ aṣa ati iṣẹ ilẹ Yoruba ati lati ṣafihan rẹ faraye ri.
Qudus Onikẹku sọ pe, ọdọ ti ko ba ti i wọnu gbọngan aṣa naa ko mọ nnkan to padanu. O ni, awọn itan adayebaye tẹlomin-in o gbọ ri wa ninu ibudo aṣa naa bakan naa ni nnkan iṣẹmbaye apewawo kunnu rẹ bamubamu.
Ọkunrin naa ti gomina kede gẹgẹ bi Oludari agba fun ibudo aṣa naa, rọ awọn ọdọ lati mu gẹgẹ bi ogun ibi wọn kiwọn si tọju rẹ daadaa nitoripe awọn naa nibẹ wulo fun.
Comments
Post a Comment