Iṣẹ́ pọ̀ fúnwa láti ṣe lórí ààtò ìlú-Sanwó-Olú
Ọlaide Gold
Erongba wa ni lati sọ ipinlẹ Eko di ilu nla tawọn oloyinbo pe ni, 'Mega City' nitori naa, iṣẹ pọ fun wa lati ṣẹ lori aato ilu. A gbọdọ gbaradi fawọn ayipada tilu nla ma n mu lọwọ.
Gomina Eko, Babajide Sanwo-Olu lo sọrọ naa nibi eto ọlọjọ meji kan tileeṣẹ ijọba to n mojuto aato ilu ṣe lọjọ kẹẹdogun oṣu yii ni Eko Hotels l'Ekoo.
Sanwo-Olu sọ pe, bi a ba n sọrọ nipa ilana tiwọn fi n da ilu nla mọ lagbaye, aato ilu jẹ akọọkọ. " Bi a ba n sọrọ ilu nla, a gbọdọ ni akọsilẹ eeyan tiwọn wa ni agbegbe kan atawọn nnkan amayedẹrun tawọn eeyan maa nilo lagbegbe yẹn, kiiṣe ki wọn bẹrẹ sii kọ nnkan ti ko si ninu iwe aṣẹ sori ilẹ.
O ni, adari ẹka to n mojuto aato ilu gbọdọ mu ọrọ naa bi iṣẹ nitori ojuṣe rẹ ni lati jẹ kawọn eeyan mọ iwọn ibi ti wọn le kọle de ati ijiya to wa fun ẹni to ba ṣe sofin aato ilu.
Gomina Eko tẹlẹ, Babatunde Fashola ninu ọrọ tiẹ ni, ẹka ileeṣẹ ijọba to n mojuto aato ilu lo gbọdọ tọkasi ilẹ to wa fun ọja kikọ, ileewe, ileewoan, gbọgan sinima, ile igbafẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Gẹgẹ bi ọrọ rẹ 'Alawada ni pupọ ninu awọn to n polowo ilẹ fun tita lasiko yii, wọn ko ni aato rara, ojuna kan pere niwọn ma n fi silẹ fun iwọle ati ijade eyi to tako ilana aato ilu nitoripe ojuna kan kọ lo gbọdọ wọlu.
Gomina Sanwo-Olu ni, ko saaye fun awitunwi asan mọ, o ni ki ẹka to n mojuto aato ilu mu iṣẹ wọn ni pataki.
.
Sanwo-Olu ni, kawọn ẹka ileeṣẹ ijọba to n mojuto ile kikọ ṣe adinku iwe aṣẹ tawọn araalu le gba kiwọn to kọle paapaa julọ awọn tiwọn fẹẹ da ileeṣẹ silẹ, o ni iru iwa bẹẹ le ṣakoba fun idagbaoke ilu.
Ni bayii, gomina ti kede ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kejila ọdun yii gẹgẹ bi afikun fawọn onile ati abanikọle lati gbawe ẹri ikọle nipinlẹ naa.
Comments
Post a Comment