Ìpínlẹ̀ Èkó kéde ìwòsàn ọ̀fẹ́ fún àìsàn ikọ́ ife
- Get link
- X
- Other Apps
Ọlaide Gold
Gẹgẹ bi akọsile awọn onimọ oluṣewadii, o han gbangba pe, ikọ ife wọpọ laaarin awọn eeyan tiwọn ko fi bẹẹ ni anfaani si itọju to peye. Eyi ma n jẹ ki ogunlọgọ sọ ẹmi wọn nu latari ailowo lọwọ lati fi ṣetọju aisan naa.
Lati gbogun ti aisan yii ko le dinku tabi ko kuro nilẹ patapata ni ẹka akojanu aisan ikọ ife pẹlu ifọwọsopọ iyawo gomina Eko ti ṣetan lati gbogun ti aisan naa lawujọ
Gẹgẹ bi ọrọ Abilekọ Ibijọkẹ Sanwo-Olu, ikọ ife jẹ aisan to ti n ja raninranin nilẹ tipẹ to si n fẹ amojuto gidi. Idi niyẹn to fi ṣe pataki lati kun awọn eeyan lọwọ lati gbogun ti aisan naa ko le kuro nilẹ kiakia.
Sanwo-Olu ni, gẹgẹ bi akojọpọ akọsilẹ awọn to n koju ikọ fehe lagbaaye, ẹgbẹẹgbẹrun lo n koju aisan yii nilẹ Afirika ti aisan naa si n ba ẹgbẹrun lọna mejidinlogun eeyan finra nipinlẹ Eko nikan gẹgẹ bi iwadii to hande lọdun 2023.
Awọn alaga jiọba ibilẹ lobinrin atawọn iyawo alaga ijọba ibilẹ kaakiri ipinlẹ Eko niwọn ma jẹ aṣoju tiwọn si ma ṣiṣẹ takuntakun lati le aisan naa wọgbẹ.
Bakan naa ni ibudo ayẹwo maa wa kaakiri ijọba ibilẹ kọọkan nibi tawọn to ba ni aisan naa ti ma gba itọju lọfẹẹ.
Yatọsi ibudo ayẹwo yii, ijọba tun ti pese awọn ọkọ ti yoo maa lọ kaakiri agbegbe kọọkan lati ṣe ayẹwo fawọn eeyan tabi lati gbe alaisan lọ sileewosan ni pajawiri.
Sanwo-Olu sọ pe, oun kede ọrọ naa gẹgẹ bi aṣoju akọọkọ fun iwosan ikọ yii nipinlẹ Eko, o ni kawọn oṣiṣẹ eleto ilera jẹ ko di mimọ pe ọfẹẹ ni iwosan rẹ koda o ni kiwọn tọ awọn oniṣegun ibilẹ lọ lati fi to wọn leti pe, ki wọn tete darii onibara to ba gbe aisan naa wa sọdọ wọn fun itọju lọ sile iwọsan.
- Get link
- X
- Other Apps
Comments
Post a Comment