Ayẹyẹ Òmìnira: Sanwó-Olú ṣèlérí ìgbé ayé ìrọ̀rùn fáwọn olùgbé Èkó


 
Ọlaide Gold

Gomina ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Babajide Sanwo-Olu, ti pe fun ẹmi ifẹ ati ifọkansin to le mu idagbasoke ba orileede Naijiria.  

Sanwo-Olu, sọrọ naa lọjọ Tuside ọjọ kin-in-ni oṣu yii lasiko ayẹyẹ ajọdun ominira ọdun kẹrinlelọgọta orileede yii, eyi to waye nileejọba ni Marina.

Nibi eto naa ni gomina ti pe fun iṣọkan ati ẹmi ifẹ to le to orileede sawujọ awọn aṣaaju lagbaaye.

 Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, ayẹyẹ ayajọ orileede wa fun lati ṣaṣaro ibi ti iṣakoso orileede duro de ati ibi to yẹ ko wa bayii . "Lonii, a korajọ lati sami ayẹyẹ ọdun kẹrinlẹlọgọta ti orileede Naijiria ti gba omiiran lọwọ awọn oyinbo amunisin. O jẹ asiko arojinlẹ lori awọn iṣoro taa ti la kọja gẹgẹ bi orileede atawọn aṣeyọri aritọkasi tawọn aṣaaju ti ṣe.

Gomina ni, kiiṣe aṣiiri to bo pe awọn eeyan n koju iṣoro paapaa julọ lori ọwọngogo ounjẹ ati epo bẹntiroolu to gbodekan ṣugbọn didun ni ọsan yoo so laipẹ. O ni, oun ati igbimọ iṣejọba oun n ṣiṣẹ laisinmin ki gbogbo nnkan le dẹrọ ati lati fawọn araalu ni aabo yo peye.

 



Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, 'Abiku' si ede Yoruba.