Cowlso: Sanwó-Olú ṣèlérí ìrànlọ́wọ́ lórí ètò ọ̀gbìn

Ọlaide Gold

Aṣekagba apejọ iyawo awọn oṣiṣẹ ijọba Eko, Cowlso waye l'Ọjọru Wẹside pẹlu ara lọkan-o-jọkan. awọn obinrin turaka koda ijo wọn to dọgba ko jẹ ka da olowo mọ yatọsi talaka, gbogbo wọn niwọn fidunnu han lara ọtọ.
Oriṣiiriṣii idanilẹkọọ lo waye nibẹ, awọn oludanilẹkọọ naa sọrọ nipa ibagbepọ awujọ paapaa julọ, ṣiṣetọju awọn ọmọ tawọn obi wọn ko lagbara lati ran lọ sileewe ati ṣiṣe abẹwo sile awọn ọmọ alainiya bakan naa ni idanilẹkọọ waye fawọn obinrin tiwọn nifẹẹ lati ṣeto ọgbin ati idokowoo.
Alaga Cowlso, Abilekọ Ibijọkẹ Sanwo-Olu,iyawo gomina ipinlẹ Eko dupẹ lọwọ gbogbo awọn tiwọn wa sibi apejọ naa, awọn iyawo awọn gomina Eko tẹlẹ atawọn iyawo gomina tiwọn wa lati ipinlẹ mi-in.
Ibijọkẹ ni, kawọn obinrin ṣamulo awọn ẹkọ tiwọn kọ ninu apejọ naa lati mọ igbesẹ to kan lati gbe ninu irinajo itẹsiwaju. Ati paapaa ki wọn mu eto ọgbin ni pataki lati le ebi ati iṣẹ wọgbẹ.

Gomina Sanwo-Olu, nigba to n sọrọ nibi  aṣekagba ayẹyẹ naa fidunnu rẹ han bi eto naa ṣe lọ bakan naa lo dupẹ lọwọ awọn tiwọn faaye silẹ lati kopa, o ni, o dajupe bi wọn ba ma pada wa sibi ayẹyẹ ẹlẹẹkẹẹdọgbọn ti yoo waye lọdun to n bọ, wọn ti ma ni aṣeyọri rere biwọn ba ṣamulo awọn ẹkọ tiwọn kọ nibi apejọ naa.
Sanwo-Olu tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe, awọn obinrin ni opomulero nitori naa ki wọn gbiyanju lati mu ida marundinlogoji ninu iṣejọba ipinlẹ ati tijọba apapọj


Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, 'Abiku' si ede Yoruba.