Cowlso: Àwọn gómìna ní kí wọ́n fáwọn obìnrin lánfààní ìṣèjọba
- Get link
- X
- Other Apps
Ọlaide Gold
Gomina ipinlẹ Akwa Ibom, Umo Eno, Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu atawọn alẹnulọrọ lawujọ ti pe fun fifun awọn obinrin lanfaani ninu iṣejọba ki wọn le fi ọgbọn inu wọn ran orileede lọwọ.
Aba naa waye nibi apejọ awọn obinrin kan to waye lọjọ Iṣẹgun Tuside ni Eko hotels. Apejọ ọdun yii ni ajọ iyawo awọn oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ Eko iyẹn Committee of Wives of Lagos State Officials (Cowlso) pe ni ẹlẹẹkẹrinlelogun iru ẹ. Sanwo-Olu ninu ọrọ tiẹ sọ pe, iwuri ni lati ri i bawọn obinrin ṣe pọ rẹpẹtẹ nibi eto Cowlso tọdun yii. O gboṣuba kare fawọn iyawo gomina Eko tẹlẹ bi wọn ṣe duro ti alaga Cowlso bayii, Abilekọ Ibijọkẹ Sanwo-Olu lati lati ṣe aṣeyọri.
Gomina mẹnuba awọn aṣeyọri rẹ paapaa julọ riro awọn obinrin lagbara atawọn nnkan mi-in lati fun awọn obinrin ni igbe aye irọrun.
Alaga Cowlso, Abilekọ Ibijọkẹ Sanwo-Olu naa dupe lọwọ gbogbo awọn iyawo gomina tiwọn wa sibi apejọ naa ati iyawo aarẹ orileede yii, Sẹnetọ Olurẹmi Tinubu fun atilẹyin rẹ.
O ni, oriṣiiriṣii ọna ni Cowlso ti gba ran awọn obinrin lọwọ paapaa julọ labala eto ọgbin yala lati ṣe ọsin adiyẹ tabi ọsin ẹja ki ebi le tan nilu.
- Get link
- X
- Other Apps
Comments
Post a Comment