Ìpínlẹ̀ Èkó ti pèsè ààyè írọ̀rùn fún ìdókòwò-Sanwó-Olú
Gomina Babajide Sanwo-Olu ti jẹ ko di mimọ pe, ipinlẹ Eko ati ijọba apapọ ti pinnu lati pese ayika to maa faaye gba awọn oludokowo lati ilẹ okeere siwaju sii.
Sanwo-Olu sọrọ naa nigba to gbalejo awọn olodokowo naa nibi ipade okowo kan ti wọn pe ni International Business Conference & Expo 2024 ti ajọ awọn olokoowo ati ileeṣẹ l’Ekoo, Lagos Chamber of Commerce and Industry, LCCI ṣagbatẹru ẹ, eyi fi sọrii idokowo ni Naijiria iyẹn ‘Invest in Nigeria’ to waye ni gbọngan Eko Hotels.
Sanwo-Olu gẹgẹ bi ọrọ rẹ nigba to n bawọn aṣoju lati ilẹ okeere sọrọ nibi eto naa sọ pe,ijọba Eko ti gbe awọn igbesẹ ti yoo mu ki idokowo rọrun nipinlẹ naa“ A fẹẹ kọ ile ikounjẹsi to tobi ju nilẹ Afirika bakan naa ni a tun fẹẹ ṣeranwọ labala eto irinajo afẹ, a ti fọwọsowọpọ pẹlu ijọba apapọ lati ṣe atunkọ gbọngan aṣa apapọ to ti di Wọle Ṣoyinka Cultural Centre of.Arts bayii. Bakan naa ni a fẹ pese aaye ikẹkọọ imọ ẹrọ fawọn ọdọ wa nitoripe afojusun wa ni lati di ibudo apewaawo fun imọ ẹrọ lagbaaye’.
Ninu ọrọ tiẹ,Adegboyega Oyetọla, Minisita to n ṣakoso ọrọ aje ori omi ṣalaye pe,ijọba apapọ ti ṣetan lati pese aaye ti yoo mu ki nnkan rọrun fawọn oludokowo lati ilẹ okeere eyi ti yoo mu ki ọrọ aje etikun ilẹẹwa tẹsiwaju si i.
Oyetọla ni, lati mu ki nnkan rọrun funidokowopọ, ijọba apapọ ti ṣi awọn ferese kan silẹ gẹgẹ atura bii amojukuro lori owo ẹru to n wọle, pipese ohun amayedẹru fun irọrun idokowo ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, ijọba apapọ tun ti bẹrẹ atunkọ awọn ibudo ọrọ aje etikun bii Apapa ati Tin-Can fun irọrun idokowo.
Comments
Post a Comment