Èkó ò sùn o, àwọn èèyàn ti padà sẹ́nu iṣẹ́ wọn
Ọlaide Gold
Beeyan ba lọọ pẹ ko to jade l'Ekoo bayii, inu gosiloo lo ti maa bara ẹ nitoripe, Eko ti ji,wọn o sun rara, awọn eeyan ti muṣẹ wọn bi iṣẹ. Ojuna mọto kun fọfọ bayii atipe awọn oṣiṣẹ ijọba paapaa o raaye iregbe mọ ni Alausa latari iṣẹ to pọ lori tabili wọn. Bakan naa ni ẹsẹ ko gbero laarin ọja mọ l'Ekoo nitoripe,karakata ti bẹrẹ ni pẹrẹu ni gbogbo ọja.
Ọjọ Aje, Mọnde, ni ipade awọn ọmọ igbimọ alaṣẹ Eko waye ni ọfiisi ijọba ni Alausa, n'Ikẹja, Gomina Sanwo-Olu lo dari ipade naa eyi to lọ wọọrọwọ laisi idiwọ kọkan.
Iwọde to waye fun ọjọ mẹta,eyi tawọn ọmọ orileedee yii fẹhonuhan si iṣejọba Aarẹ Bọla Tinubu, nitori ọwọngogo ounjẹ ati epo bẹntiro to gbode kan naa lo ṣe idiwọ tawọn eeyan ko fi le lọ sibi iṣẹ oojọ wọn.
Lọjọ Aiku, Sannde ni Aarẹ Tinubu ba gbogbo ọmọ orileede Naijiria sọrọ, o ni, oun mọ ẹdun ọkan wọn ṣugbọn ki wọn mu suuru diẹ si nitoripe, ọsan yoo bẹrẹ si so didun laipẹ.
Ninu ọrọ Kọmiṣanna fun eto iroyin nipinle Eko, Gbenga Ọmọtọṣọ, nigba to bawọn oniroyin sọrọ ni Alausa lọjọ Aje, Mọnde, o ni, awọn olugbe Eko ti pada sẹnu iṣẹ wọn bẹẹ ni wọn o ṣetan lati padanu dukia ijọba kọkan sọwọ awọn ọmọ ganfe tiwọn fẹẹ fi iwọde boju lati ṣiṣẹ ibi wọn.
Ọmọtọṣọ ni, ijọba Eko fi awọn nọmba ipe mẹta kan lede eyi tawọn eeyan fi ma ni anfaani ba ijọba sọ ẹdun ọkan wọn tiwọn si ti n ṣamulo rẹ lati ba ijọba sọrọ to maa ṣe ipinlẹ naa ni anfaani.
.
Comments
Post a Comment