Oríire nlá ni ìpàtẹ ọrọ̀ aje jẹ́ fún àwọn oníṣòwò abọ́ọ́dé l'Ékòó


 Ọlaide Gold

Nnkan maa bẹrẹ sii ṣẹnuure fawọn olokoowo keekeeke taa mọ si Micro, Small and Medium Entreprenuers, (MSMEs) paapaa julọ awọn ọdọ tiwọn wọn n ṣe katakara ọrọ ajẹ latari bi ijoba ipinle Eko ti ṣeleri atilẹyin fun wọn.

Gomina Babajide Sanwo-Olu ti ṣetan lati kun awọn  oniṣowo abọọde lọwọ ati lati ṣi ferese silẹ lati kofa anfaani to maa jẹ ki ọrọ aje rọrun fun wọn lati ṣe.

Idris Arẹgbẹ,Olugbaninimọran fun gomina lori irinajo afẹ, aṣa ati iṣe,lo fi iroyin naa lede lọjọ kẹrinla, ọjọ Ẹti Furaide to kọja nibi eto ipatẹ afẹ kan ti wọn pe ni Lagos Tourism/Naija Brand Chick, to waye ni Ikẹja. Nibẹ lo ti ṣalaye pe, gbogbo ọna ni ijọba Eko labẹ iṣakoso gomina Babajide Sanwo-Olu ti la kalẹ lati ṣe iranlọwọ to peye fun okoowo wọn.

Ninu ọrọ ẹ, Arẹgbẹ ni, ijọba ti ṣetan lati ni ajọṣepọ to dan mọran pẹlu awọn olokoowo abọọde  atawọn onileeṣẹ aladani ninu ipatẹ ọlọjọ mẹta naa atipe owo  ti yoo ti ibi ipatẹ naa jade yoo le ni biliọnu marun-un naira.

Biba lawọn eeyan pejupẹsẹ sibi ipatẹ ọrọ aje naa ti onikaluku si n ṣe aniyan ọrọ aje rẹ lọ pẹlu ifọkanbalẹ tawọn ero tiwọn wa raja si n gboṣuba kare fawọn to ṣe onigbọwọ ipatẹ naa latari bi wọn ṣe ni anfaani lati ra ọja ni owo ti ko da wọn ni apo lu.

Nigba toun naa n sọrọ nibi ipatẹ ọhun, ẹni to ṣagbatẹru eto ipatẹ NBC naa, Abilekọ Nelly Agbogu, ni ajọṣepọ pẹlu ijọba Eko lo fẹsẹmulẹ julọ paapaa bi awọn oloowo keekeeke atawọn onileeṣẹ adani ṣe tu yaayaa jade lati wa kopa ninu ipatẹ naa ti wọn si n pa ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu naira.

Awọn laamilaaka ti wọn wa nibi ipatẹ ọrọ aje naa ni,Iyalaje Oodua,Ọmọọba Toyin Kọlade, Abilekọ Jumọbi Adegbẹsan-Damijo atawọn mi-in

 

 

 

 

 

 


Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Sanwó-Olú ṣèlérí ètò ìrànlọ́wọ́ láti sàmì àyájọ́ àwọn obìnrin lágbàáyé