Ọ̀rọ̀ ọba jíjẹ di wàhálà nílùú Igbóoyé,wọ́n ní Sanwó-Olú nìkan ló lè bá wa yanjú ẹ̀
Ọlaide Gold Lọwọlọwọ bayii, ibẹrubojo lawọn araalu fi n rin nilu Igbooye nijọba ibilẹ onidagbasoke Eredo l'Ẹpẹ,ipinlẹ Ogun. ko si nnkan meji to fa a ju ọrọ ọba jijẹ lọ. Gẹgẹ bi nnkan tawọn araalu naa sọ, ọkunrin kan torukọ ẹ n jẹ Wasiu Musa Adebamọwọ ni o n da rukerodo silẹ, wọn ni ṣe lo n sa gbogbo ipa to ni lati gbe aburo ẹ Ọgbẹni Rasak Musa Adebamọwọ sori itẹ gẹgẹ bi ọba leyi tawọn eeyan koro oju si. Ninu ipade tawọn ẹbi ṣe pẹlu awọn oniroyin lọjọ Ẹti Furaide to kọja ni ọkan lara awọn agba ilu, to tun jẹ akọwe idile Erelu, Ọtunba Anthony Oguntimẹhin, ti ṣalaye pe, idile mẹrẹẹrin to n jọba ni Igbooye lo yan ọba to wa lori itẹ lọwọlọwọ iyẹn Ọba Michael Gbadebọ Ọnakọya beeni kabiyesi gun ori itẹ baba nla rẹ lẹyin tawọn afọbajẹ pari gbogbo igbesẹ to yẹ. "ohun kan to daju ni ilẹ yoruba ni pe, bi ọba kan ko ba ku,ọba mi-in o le jẹ." Bakan naa ni, Ọgbẹni Julius Adenuga lawal, adari kan ninu ẹbi Ewade ni, bo tiẹ jẹpe ẹjọ ṣi wa ni kọọtu nibiti, Ọba Micheal Gb...