Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó faramọ́ kí ọmọ gbọ́njú dáadáa kó tó wọ iléèwé gíga
Ọlaide Gold
Ijọba ipinle Eko ti ṣegbe lẹyin aba kan to waye pe; ọmọ tọjọ ori ẹ ba ti to ọdun mejidinlogun nikan lo gbọdọ lanfaani lati wọ ileewe giga yunifasiti tabi ileewe gbogboniṣe taa mọ si politẹkniiki. Aba naa ni, ọmọ gbọdọ ni oye ibagbepọ daadaa ko to damọran ipele to kan ni ẹka ẹkọ.
Kọmiṣanna fun ẹka ẹkọ lawọn ileewe giga Eko,Ọgbẹni Tọlani Sule, lo sọrọ atilẹyin naa lasiko to n jabọ iṣẹ iriju rẹ fawọn oniroyin lati sami ayẹyẹ ọdun kan saa ẹlẹẹkeji Gomina Babajide Sanwo-Olu,eyi to waye ni Alausa, n’Ikẹja l’Ekoo.
Bẹo ba gbagbe, laipẹ yii ni minisita fun ẹka ẹkọ,Ọjọgbọn Tahir Mamman,sọrọ naa pẹlu alaye pe, ijọba apapọ n ṣiṣẹ lọwọ lori gbedeke ọjọ ori ọmọ to le tẹsiwaju lẹka ẹkọ nileewe giga. Bakan naa lo rọ awọn obi; ki wọn dẹkun lati maa ti ọmọ ti ko tii balaga daadaa tọjọ ori wọn ko tii pe ọdun mejidilogun saarin awọn to gbọn ju wọn lọ. Ọkunrin naa ni, bi igba teeyan mọ ọn mọ ti agutan saarin awọn kinihun ni biwọn ṣe ma n ti awọn ọmọ wọn sita laibikita ewu to wa nibẹ.
Mamman sọrọ naa lẹyin to ri esi idanwo tawọn akẹkọọ n ṣe wọ ileewe giga iyẹn Unified Tertiary Matriculation Examination (UTME) lawọn ibudo idanwo kan l’Abuja, o koro oju si bawọn akẹkọọ tiwọn jokoo nibi idanwo naa ṣe je awọn ọmọ tiko tii janu lẹnu ọmu tiwọn si n gbaradi lati wọ ileewe giga.
Sule, ninu ọrọ rẹ sọ pe, ijọba ipinlẹ Eko ti ṣetan lati ṣatilẹyin aba naa, o ni akẹkọọ jade gbọdọ le koju iṣoro to ba waye lẹyin to pari ẹkọ rẹ tan nitoripe ati kawe gboye ko ṣoro bi koṣe ati koju iṣẹlẹ awujọ leyi to maa ṣoro diẹ fun ọmọ tọjọ ori rẹ ko to nnkan.
Comments
Post a Comment