Wàhálà n rúgbó bọ̀ láàrin Ifẹ̀ àti Mọdákẹ́kẹ́:Àwọn agbébọn pa ọmọọba, wọ́n tún gé apá rẹ̀ lọ
Ọmọlọla Oluwapẹlumi
Bi awọn to lẹnu nipinlẹ Ọṣun, paapaa niluu Ile-Ifẹ ati Mọdakẹkẹ, ko ba fọgbọn to ọrọ ọhun, afaimọ ki wahala tuntun ma tun bẹrẹ laarin awọn ilu mejeeji. Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja ni rogbodiyan tuntun yii bẹrẹ ni abule kan ti wọn n pe ni Wanisani, niluu Ile-Ifẹ, nigba ti awọn afurasi agbebọn kan da ẹmi Ọmọọba Adesọji Josiah Adedire, ti wọn ni agboole Ọba Adesọji Aderẹmi lo ti wa legbodo. Bo tilẹ jẹ pe ariwo tawọn ọmọ ilu Ile-Ifẹ n pa ni pe awọn mọ pe awọn Mọdakẹkẹ lo wa nidii iku Ọmọọba Adedire, sibẹ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun ti tako iroyin yii.
Awọn tiṣẹlẹ ọhun ṣoju wọn ṣalaye pe akọlu ti wọn ṣe si oloogbe yii lagbara pupọ, atipe awọn agbebọn yii tun da ẹmi eeyan meji mi-in legbodo labule to wa nitosi Wanisani, iyẹn abule Alọfẹ.
Ṣe ni wọn tun dana sun ile kan pẹlu kẹẹkẹ ti i ṣe ti Ọmọọba Adedire, ti gbogbo rẹ si jona guruguru ko too di pe wọn tun ṣe awọn eeyan mi-in leṣe yannayanna.
Nigba ti ọkunrin kan torukọ rẹ n jẹ Samuel, ẹni tori ko yọ lasiko tawọn to pa Oloye Adedire yii n ṣalaye bọrọ ṣe jẹ, ṣe lo ni "akọlu ọhun buru jai, koda awa tori ko yọ gan-an farapa yannayanna. Niṣe lawọn to ṣakọlu ọhun ko ada, ibọn pẹlu awọn ohun ija oloro mi-in wa."
Ninu ọrọ Ọgbẹni Dare Ademiju to jẹ mọlẹbi Oloye Adedire ti wọn da ẹmi rẹ legbodo, ṣe lo ni "niṣe lawọn agbanipa yii ko ada, ibọn atawọn ohun ija oloro mi-in lọwọ. Mi o mọ ibi ti awọn ti ki i ṣe ṣọja ti le ri iru ibọn bẹẹ."
Ẹnikan to wa pẹlu Ọmọọba Adedire nigba tiṣẹlẹ yii ṣẹlẹ, iyẹn Samuel, ni pe ọdọ oun ni oloye ọhun wa nigba ti awọn fi bẹrẹ si i gbọ ti iro ibọn n dun lakọlakọ. Abule Wanisani yii jẹ ọkan ninu awọn abule ti wọn ni idile Ọba Aderẹmi n dako si. Samuel ni iro ibọn ti awọn gbọ yii lo jẹ kawọn fara pamọ ṣugbọn nigba tawọn ri ọkunrin to n ta ẹmu kan, tọpọ eeyan mọ si Baba Ghana, to kọja lo jẹ kawọn jade sita. O ni Baba Ghana yii lo ni pe awọn Mọdakẹkẹ lo n yinbọn ṣugbọn wọn ti kọja lọ. Ko pẹ ti Baba Ghana fi wọn silẹ ni awọn agbebọn yii yọ lojiji ti wọn si rọjo ibọn le Oloye Adedire lẹyin nibi to ti n gbiyanju lati gbe kẹẹkẹ rẹ salọ. O ni "bi a ṣe gburoo ibọn ni a sa, ṣugbọn nigba ti a ri Baba Ghana, a bọ sita lati bi i leere ohun to ṣẹlẹ.Ṣe lo ni ko si nnkan kan atipe awọn Mọdakẹkẹ kan lo n kọja lọ ti wọn fi n yinbọn soke. Ko to iṣẹju marun-un ti Baba Ghana fi wa silẹ la ri i tawọn kan n ya bọ latoke, koda, Oloye Adedire lo kọkọ ri wọn. Ṣugbọn ṣa, ko too sọ pe oun yoo ta sori kẹẹkẹ rẹ pe koun sa, awọn apaayan yii ti rọjo ibọn bo o."
Alaye ti Dare ati Samuel ṣe yii lo fa a ti awọn eeyan fi n fura si Baba Ghana, wọn lo ṣee ṣe ki ọkunrin ọhun mọ nipa iṣẹlẹ yii, atipe boya oun lo n ṣe ami fun awọn Mọdakẹkẹ labule Wanisani.Gẹgẹ bi GBÉLÉGBỌ́ ṣe gbọ, awọn ọlọpaa ti mu Baba Ghana, wọn lo si ti darukọ awọn kan pe wọn mọ nipa iṣẹlẹ ọhun. Akọroyin wa gbọ pe lẹyin ti awọn afurasi yii pa Oloye Adedire, ṣe ni wọn gbe oku rẹ lọ.
Ọgbẹni Dare ni ṣe lawọn pe aafin Akọraye ti ilu Mọdakẹkẹ lori ọrọ yii, lẹyin naa ni wọn si too gbe oku ọkunrin ọhun silẹ, koda Baba Ghana lo mu awọn lọ sibi ti oku ọhun wa. Eyi lo jẹ ki ileeṣẹ ọlọpaa mu Baba Ghana, o si ti ṣalaye bọrọ ṣe jẹ fawọn ọlọpaa to wa niluu Oṣogbo l'Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja. Ṣa, Yẹmisi Ọpalọla to jẹ alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun loun o ti i gbọ nipa iṣẹlẹ ọhun rara.
Comments
Post a Comment