Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ògbólógbòó ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn l'Ọ́ṣun
Adesọla Adunni
Lati lee peese aabo to peye fun araalu nipinlẹ Ọsun ati layika rẹ, ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun ti sawari ogbologboo ọmọ ẹgbẹ okunkun kan, to tun asekupani ti wọn ti n fọjọ pipẹ wa kaakiri, Bode Ọlakayọde, ti inagijẹ rẹ n jẹ Bọde Ìtaàpá.
O pẹ ti ileesẹ ọlọpaa ti n wa ọkunrin naa, ṣugbọn nigba to di osu Keje, ọdun 2022, ni fi ikede gbangba sita pe awọn n wa ọmọkunrin naa ni wajowajo lẹyin ifẹsunkan fawọn iwa ọdaran to ti hu loniruuru. Afurasi ọdaran ọhun, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn ni wọn fẹsun to ni i se pẹlu ipaniyan, jijẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun, idigunjale, igbigbimọ-pọ huwa buburu atatawọn ẹsun ọdaran mi-in kan.
Lọdun 2022 ni Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Ọsun, Yẹmisi Ọpalọla, fi atẹjade kan lede pe Bọde ti sọ ara rẹ di ẹrujẹjẹ siluu Ileṣa, to si n da wahala silẹ laarin ilu lai bẹru ofin, bẹẹ ni wọn tun kede ẹbun nla fẹnikẹni to ba le tu aṣiri ibi ti ọdaran naa farapamọ si fun ileeṣẹ ọlọpaa, atipe ẹnikẹni tọwọ ọlọpaa ba tun tẹ pe o saabo fun ọkunrin naa yoo koju idajọ. A ti asiko ọun ni wọn si ti n dọdẹ afurasi naa kaakiri ipinlẹ Ọṣun, ko too di pe ọwọ tẹ ẹ.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, abule kan ti wọn n pe ni Orógójì, to wa nijọba ibilẹ Ila-Oorun Atakunmọsa, nipinlẹ Ọṣun naa lọwọ ti pada tẹ ẹ lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu to kọja yii. Awọn ọmọ ikọ ọlọpaa, ẹka to n gbogun ti awọn ajinigbe ati idigunjale, "Anti-Kidnapping Squad" ni wọn lepa rẹ de abule naa, ti wọn si wa a jade nibi to sa pamọ si.
Nigba to n fidi ọrọ naa mulẹ, Alukoro ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọsun sọ pe, loootọ ni ọwọ ti tẹ Bọde, ṣugbọn oun ko le sọ pupọ lori rẹ lasiko yii, nitori iwadii ṣi n tẹsiwaju.
Amọ sa, bi awọn araalu se gbọ pe awọn agbofinro ti mu ọkunrin naa ni wọn ti bẹrẹ sini yọọ, nipatakijulọ, niluu Ilesa. Wọn ni ọpọlọpọ iyawo ile ni ọku rin naa yo sọdi alai-lọkọ ti ọpọlọpọ ọmọ sidi alai-lobi nipasẹ iwa ipaniyan loniruuru toti hu. Wọn ni awọn oloselu lo n gbe sẹ fun ọkunrin naa bẹẹ ni ẹnilẹni toba ti kọwe iku si, kẹni naa o ya tete filuu silẹ fun ni, toripe seni yoo maa lepa rẹ kiiri.
Araalu ti wa a gbosupa fun ileesẹ ọlọpaa fun akitiyan wọn lati fun bi wọn se ri ọkunrin naa mu, ti wọn si ni ki wọn ri i daju pe ko salọ lakolo wọn, nitoripe ageku ejo lọkunrin naa, to ba fi le jajabọ,wahala nla lo tun de ba araalu nipinlẹ Ọṣun.
Comments
Post a Comment