Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀: Ìdágbére tí kò lópin (1)


Mo mu akọle ọrọ mi toni ninu ọrọ apilẹsọ ti Ọjọgbọn Adebayọ Williams sọ ni nnkan bii ogun ọdun diẹ  sẹyin. Ni ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹta, ọdun 2004, ni ẹgbẹ Afẹnifẹre pe ọjọgbọn yii ko waa ṣe ipilẹṣẹ ọrọ apilẹsọ ni iranti oloogbe Ọbafẹmi Awolọwọ, ẹni to ti figba kan jẹ pirẹmia Iwọ-Oorun ti i ṣe awọn ipinlẹ marun-un; Ọyọ, Ogun, Ondo, Ekiti ati Eko lakoko yii.

Idi meji ni ẹgbẹ yii ṣe gbe igbesẹ yii, idi akọkọ ni lati fi ami ẹyẹ ti awọn alakooso ‘Awo Foundation’ da silẹ lati fi yẹ ẹni kẹni to ba ti ṣe iṣẹ takuntakun  fun ara ilu nigba to ba di ipo nla kan mu. Ami ẹyẹ yii ki i ṣe fun olṣelu tabi fun ẹni to lowo lawujọ bi ko ṣe ẹni ti gbogbo eeyan ri pe ọmọluabi ni ati pe gbogbo ipa ati agbara to ni lo fi ran ilu lọwọ eyi ti tẹru- tọmọ le e foju ri. Idi keji ni lati maa ṣe iranti awọn iṣẹ manigbagbe ti  Awo gbe ṣe ninu oṣelu Iwọ-oorun ati oaijiria ki o to gbekuru jẹ lọwọ ẹbọra.

Ni ayajọ ọjọ yii ni oṣu kẹta, ọdun 2024, ni wọn fi ami ẹyẹ yii da Ọmọwe Akinwumi Adeṣina, ẹni to ti figba kan ṣe minisita fun eto ọgbin ni aye ijọba Goodluck Jonathan ko too di ipo alakooso fun banki apapọ tilẹ Afirika(Africa Develoment Bank) to n ṣe lọwọwọ bayii, mu.

Ni akoko ayẹyẹ yii to waye niluu lbadan, o fẹrẹ ma si awọn ọtọkulu ti ko pe sibẹ lati ba Adeṣina dawọọ idunnu pe wọn fi iru ami-ẹyẹ eyi ti ko wọpọ bayii yẹ ẹ si nigba to wa loke eepẹ. Lori awọn oloṣelu jakanjakan, to fi de ọdọ awọn ogunna gbongbon ninu eto ọrọ aje, awọn lọba-lọba ati awọn eeyan pataki laarin ilu yala to wa nipo agbara lakooko yii tabi to ti fẹyinti, bẹẹ ni ogunlọgọ awọn gomina tuntun ati awọn to ti figba kan logba ko gbẹyin nibi apejẹ nla yii.

Ohun to jẹ iyalẹnu fun mi nibi apejẹ yii ni ọgọọrọ awọn to n pe ara wọn ni ẹgbẹ Afẹnifẹre ti wọn pejọ sibẹ, ti awọn kan ninu wọn si de fila iru eyi ti Awo maa n de nigba aye rẹ lati fi han fun gbogbo awọn to peju nibẹ pe awọn lọmọ lẹyin Awolọwọ.

Ṣe Yoruba gbọn pupọ ninu iran wọn nigba ti wọn sọ pe aiṣe daadaa ara aye ni i mu ni ranti ero ọrun. Lonii tilẹ mọ yii, ko si oloṣelu yala loke eepẹ tabi to ti ku ni orilẹ-ede yii ti a le fi we Awolọwọ. O kọ ni kikọ, o sọ ni sisọ, o ṣe ni ṣiṣe, o gunyan fẹgbẹ, o tun gbawo bọ ninu ọrọ oṣelu ati imọ ijinlẹ ninu ọrọ aje debii pe ko si olokiti bii ọbọ rẹ ti ọrọ ba di ka ni laakaye lati to ilu.

Omije ja bọ loju mi nigba ti mo ri awọn ọgọọrọ awọn ti baba yii ti kọ ni dida ọwọ, ati titẹ ẹsẹ nipa oṣelu ki iku too pa oju rẹ de to pejọ sibi apejọ yii to jẹ pe kiki alabosi ni wọn, awọn perete ninu wọn to di ipo oloṣelu mu  yala gẹgẹbi gomina tabi aṣofin lo sọ ara wọn di ajẹlẹ nigba ti wọn wa nipo agbara ti wọn kan jẹ kiki fila dide lasan, ṣugbọn ti iṣesi wọn, ihuwa si wọn ati gbogbo ohun ti wọn ṣe nipo agbara yatọ gedegbe si alatẹle Awolọwọ gidi.

Ṣe tọmọde ba kọ iyan  alẹ, awọn agba aa si fitan balẹ. Ọgọọrọ awọn to pe ara wọn ni Afẹnifẹre wọnyii pẹlu fila isọnu ti wọn n de kiri  n lo orukọ Awolọwọ fun anfaani ara wọn ṣugbọn ti wọn jinna si ohun ti Awo di mu nigba to wa loke eepẹ.

Ọpọlọpọ ninu wọn to bara wọn nile aṣofin ni Abuja buru ju ejo sebe lọ nipa iwa ati iṣe wọn, ẹnu ofo lasan ni wọn fi n pariwo ti wọn si darapọ mọ awọn yooku lati lu Naijiria ni jibiti ti omi ọkọ wa si n poyi loju kan. Dipo ki wọn gbe ẹwu bi a oo ṣe fi ofin sọlu dẹrọ, ọpọlọpọ ninu wọn di kọngila ọsan gangan ti wọn si n ko owo ilu sapo lai bikita atubọtan, bẹẹ ni fila Awolọwọ ni wọn n de kiri, awọn ẹni ẹsin ti n jẹ iṣin.

Ni gbogbo ipinlẹ maraarun ti Awo ti da bii ẹdun, to ti rọ bii òwè nigbakan ri to si ni ọpọlọpọ ohun a mu tọka si ni awọn igbalode ọmọ Awolọwọ wọnyi  ko jẹ ki awọn ara ilu ni anfaani lati dibo fun ẹni to ba wu wọn, bi ko ṣe ẹni ti yoo ṣe tiwọn yala ọmọ bibi inu wọn, iyawo wọn, iyekan wọn tabi ojulumọ debii pe ireti ọmọ mẹkunnu ti ko ni anfaani kankan di ẹti ati ekurọ oju ọna.

Nigba kan ana, ohun ti ẹgbẹ Afẹnifẹre duro le lori ni lati ṣe amojuto erongba gbogbo ọmọ Oduduwa nipa ilọsiwaju wọn ati ohun ti wọn duro le lori gẹgẹbi ipinnu bii ẹkọ-ọfẹ fun gbogbo ọmọ wọn titi to fi de ileewe girama, eto ilera alabọde ti yoo wa ni ẹsẹ kuku gbogbo, eto mọ-ọn-kọ mọ-ọn-ka fun gbogbo mutu-muwa ati eto ọgbin bọluyo ti ko lafiwe, eyi ti onikaluku yoo mu dani gẹgẹbi ohun afojusun ninu ẹgbẹ yoowu ti wọn ba wa.

Ṣugbọn o ṣeni laaanu lonii pe esuro ti padi da o n le aja, Afẹnifẹre ti sọ ara wọn di ẹgbẹ awo eyi ti wọn tilẹkun  mọ awọn ọdọ iwoyi lat darapọ mẹgbẹ ti awọn agba kan agba kan ri ẹgbẹ yii bii ohun ti a fi n dunaa-dura si apo ara wọn ninu ọja oṣelu, ti wọn si fi ojoojumọ pariwo pe ti  Yoruba lawọn n ṣe.

Awọn kan tilẹ ni anfaani lati ṣe gomina ipinlẹ wọn fun saa meji, dipo ki araye ri iyatọ, oyinbo bọlugi ni wọn n sọ kiri, wọn ti gbagbe gbogbo eto ki araalu ri omi mu lai ṣe omi agbelẹrọ,(borehole). Lẹyin ti wọn kuro nipo, wọn waa n pariwo atunto ilu ati iwe ofin tuntun lo le gba Naijiria kuro ninu hilahilo to wa bayii, bẹẹ, fila ma-wo-bẹ ni wọn de nigba ti wọn wa nijọba.

Dipo ki wọn duro gẹgẹbi osusu ọwọ, ki wọn ṣe akanṣe iṣẹ ti yoo ran awọn  ipinlẹ wọnyi lọwọ yala lori eto ọkọ wiwọ, ọrọ aje tabi eto ẹkọ, ṣe ni awọn kan ninu wọn bẹrẹ papakọ ofurufu ti wọn fi ko ọpọlọpọ owo jẹ ti ko si yọri sibi kankan titi di akoko yii. O daju ṣaka pe ṣe ni Awolọwọ yoo maa sunkun ninu saare rẹ bayii.

Gbogbo ilu lo mọ pe ijọba ibilẹ lo kangun si awọn araalu ju ati pe ohun ni ipilẹṣẹ ijọba awa-ara-wa, ṣebi awọn to pe ara wọn ni atẹle Awolọwọ lo ṣofin abaadi pe ki owo ijọba ibilẹ ma a bọ sinu asunwọn ijọba ipinlẹ, ṣe ni wọn sọ ijọba ibilẹ di korofo lasan, ti wọn ko jẹ ki owo tẹ wọn lọwọ ti awọn gomina si n fi owo wọn ṣara rindin. Eleyii ko ṣẹlẹ ri lasiko Awolọwọ.

 

Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, 'Abiku' si ede Yoruba.