Àwọn olókoòwò abọ́ọ́dé má rọ́wọ́mú ńibi ìpatẹ ọrọ̀ ajé tó má wáyé l’Ékòó
- Get link
- X
- Other Apps
Ọlaide Gold
Olugbaninimọran fun gomina Eko lori eto afẹ,Ọgbẹni Idris Arẹgbẹ nigba to n bawọn oniroyin sọrọ lonii lasiko to n jiṣẹ iriju rẹ, eyi ti wọn fi sami ayẹyẹ ọdun kan Gomina Babajide Sanwo-Olu fun saa ẹlẹẹkeji, ṣalaye pe nnkan yoo ṣẹnuure fawọn olokoowo abọde lasiko yii nitori alaalẹ ti wa fawọn eto afẹ kan ti yoo dẹrin pẹẹkẹ wọn.
Nibi eto naa lo ti kede ajọṣepọ pẹlu ajọ kan ti wọn pe ni Naija Brand Chick (NBC) nibi ti gbajumọ oṣere tiata nni, Toyin Abraham-Ajeyẹmi ti sọ pe, oun fẹran lati maa ṣepọ pẹlu awọn eeyan igberiko bakan naa loun ṣetan lati rii dajupe awọn eeyan ko ere rẹpẹtẹ ninu ipatẹ naa. O wa dupẹ lọwọ awọn agbatẹru eto naa fun ajọṣepọ ti wọn fẹẹ ṣe pẹlu ijọba Eko nipa bi wọn ṣe fẹẹ fun awọn olokoowo abọọde lanfaani lati ṣafihan okoowo wọn.
Ọjọ kẹrinla si ọjọ kẹrindinlogun,oṣu kẹfa ọdun yii ni eto naa maa waye, nibẹ ni wọn ti fẹẹ fun awọn onileeṣẹ abọọde atawọn oniṣowo kara-kata ni anfaani lati ṣe ọrọ aje to maa mu owo gidi wọle funwọn.
Arẹgbẹ ni,Gomina Babajide Sanwo-Olu ni afojusun lati mu ki eto afẹ ipinlẹ Eko jẹ arikọṣe, O ni, erongba ijọba ni lati mu ilọsiwaju ba ipatẹ okoowo itagbangba,oge ṣiṣe,aṣa ati iṣe,ọṣọọ atawọn nnkan mi-in to jẹ mọ irin ajo afẹ.
O ni, nigba tawọn ba maa fi dawọle awọn eto tawọn ti la kalẹ lati ṣe,gbogbo eeyan ipinlẹ Eko ati agbegbe rẹ lo maa gboṣuba kare fun aṣeyọri to ma ṣẹlẹ lẹyin naa.
Oludasilẹ ipatẹ ọrọ aje NBC, Abileko Nelly Agboju, ninu ọrọ tiẹ naa dupẹ lọwọ ijọba ipinlẹ Eko fun anfaani ajọṣepọ naa pẹlu ileri pe ileeṣẹ naa yoo tubọ wu ijọba lori siwaju sii.
- Get link
- X
- Other Apps
Comments
Post a Comment