Aṣòfìn Abuja àti owó àkànṣe iṣẹ́: Jìbìtì tútù látọ̀dọ̀ olóṣèlú

Aṣòfìn Abuja àti owó àkànṣe iṣẹ́: Jìbìtì tútù látọ̀dọ̀ olóṣèlú

Ni nnkan bii ọdun diẹ sẹyin, mo ni anfaani lati lọọ ṣe iroyin itọpinpin lori ibi ti awọn aṣofin ba iṣẹ akanṣe eyi ti wọn gba obitibiti owo le lori ninu eto iṣuna ọdun naa de. Ṣe Yoruba bọ wọn ni ọrọ lo ko mo ba mo ro wa, gẹgẹ bii ọtẹlẹmuyẹ oniroyin atọpinpin, aṣiiri nla kan lo tu si mi lọwọ nipa iwe akojọpọ awọn iṣẹ akanṣe ti awọn aṣofin to wa ni Abuja ṣe fun ọdun meji si akoko ti mo ṣe itọpinpin yii.

Akoko yii ni mo ri i dajudaju pe ẹni a ba ta ka fi ra atupa to waa ni oun ẹni a ji tanna wo loru ni ọpọlọpọ awọn aṣofin yii. Ọpọlọpọ ko figba kankan nifẹẹ araalu, ohun ti wọn yoo jẹ ni wọn n wa kiri. Ṣe ni wọn n lo anfaani ti ilu fun wọn yii lati ṣoju wọn lati jẹun soke.

Ni kete ti iwe yii tẹ mi lọwọ ni mo ṣakiyesi pe awọn aṣofin kan to wa lati ipinlẹ lla-Oorun (South/East) ti  ṣe iṣẹ akanṣe lori àgbàrá to n da awọn eeyan agbegbe yii laamu lati ọjọ to ti pẹ. Ni mo ba gbera lati ilu Eko lọ si ipinlẹ Enugu ki n le ri ara to wa ninu iwe ti awọn aṣofin to wa lati agbegbe yii sọ pe awọn ti ṣe.

Ẹnu ko kọ iroyin nigba ti mo de ibi ti ọkan ninu awọn aṣofin to ti agbegbe yii wa  loun ṣe  awọn iṣẹ akanṣe to ti gbowo tabua fun yii, ṣugbọn ti ko si iṣẹ kankan ti eeyan le tọka si ju pe owo ti wọgbo lọ. Ṣe ni alaga ijọba ibilẹ ti iṣẹ akanṣe naa wa la ẹnu ti ko le e pade nigba ti mo fi iye owo ti wọn fi peri iṣẹ yii ṣugbọn ti wọn ko ri eegun to n jẹ Ajikẹ aṣofin yii nile debi ti yoo ṣe iṣẹ kankan han an.

Ki a ma wulẹ tẹ tufọ aja, ni gbogbo ibi ti akọroyin yii de ni akoko yii, ko si eyi to san ninu ọmọ ejo ninu awọn aṣofin wọnyi nipa iṣẹ akanṣe. Eyi ni ko fi jẹ iyalẹnu ni akoko yii nigba ti awọn aṣofin wọnyi ṣe afikun owo si owo iṣuna ti ọdun yii lẹyin ti aarẹ ti buwọ lu u tan

Ko too kuro ninu apata agbara, aarẹ ana, Muhammadu Buhari figbe ta pe  odidi ọdun mẹwaa ni awọn aṣofin yii fi gba owo akanṣe iṣẹ ni ẹsẹ kuku to  jẹ  nnkan bii tiriliọnu Naira, ṣugbọn o ṣeni laaanu pe ko si akanṣe iṣẹ kankan to han ni ẹsẹ kuku pe iru owo tabua bayii ti wọgbo atuu.

Laipẹ yii ni ajọ kan ti ki i ṣe tijọba ti wọn n pe ni BudgIT sọ pe ina ti jo dori koko ati pe nigba ti awọn ṣe iwadii ijinlẹ lori awọn owo tabua ti awọn aṣofin gba ati awọn iṣẹ akanṣe ti wọn lawọn ṣe, rẹrẹ ti run, eleru ti sungi bẹẹ ni wọn ti lu awọn ara ilu ni jibiti tutu, nitori ko si nnkan aritọkasi to kun oju oṣuwọn obitibiti owo ti wọn gba.

Eyi lo waa mu awọn lameetọ ilu sọ pe ko si ohun ti o kan awọn aṣofin nipa akanṣe iṣẹ nitori eleyii ki i ṣe ara iṣẹ wọn bi ko ṣe ki wọn ṣofin fun awọn araalu. Wọn ṣiṣọ loju eegun pe ọna jẹgudu jẹra lo sun awọn aṣofin wọnyi lati da aba buruku yii.

Yatọ si eleyii, ki lo kan lemọmu pẹlu aja digbolugi. Yoruba bọ wọn ni alangba n ṣe igbeyawo, agilinti n fọmọ fọkọ, labalaba fo fẹrẹ o ni oun yoo jo ijo ajo takiti nibẹ, ewo ninu wọn lo ba tan.Awọn aṣofin ki i se kọngila agbaṣẹṣe debii pe wọn yo gbeṣẹ alagbaṣe  fun wọn, ki waa ni iṣoro wọn? Iwa ẹgbin, ika ati wọbia ni ki awọn aṣofin fi iru owo gọbọi yii sinu owo iṣura.

Ninu iwoye rẹ, ọkan ninu awọn amofin agba to gunyan fẹgbẹ to tun gbawo bọ, to fi ilu lbadan ṣe ibudo, Niyi Akintọla sọ pe arajuka ni ki awọn aṣofin sọ ara wọn di kọngila ọsan gangan nitori owo ati pe iwe ofin ti ṣe ilana iṣẹ onikaluku laarin igun mẹta ijọba ti ko si ruju rara.

Akintọla tẹ siwaju pe iwe ofin ti ọdun 1999 ṣiṣọ loju eegun nipa iṣẹ akanṣe nigba to sọ pe ‘ki i ṣe iṣẹ aṣofin rara lati dabaa iṣẹ akanṣe ni ṣiṣe, bii ikọja aaye ni, o dabii ẹni pe aimọkan awọn araalu ati pe iwe ofin ko ye wọn daradara lo jẹ ki wọn ro pe aṣofin le e di kọngila ọsan gangan nitori pe o jẹ aṣoju ilu nile igbimọ aṣofin.’

Bo tilẹ jẹ pe o sọ pe eyi ti awọn ara ilu n ṣe ninu rẹ lo pọ nipa ki wọn lọọ maa beere awọn nnkan ti agbara aṣofin ko ka lọwọ wọn, eyi to jẹ ki awọn naa maa dọgbọn ki wọn fi wọrọkọ ṣe ada lati wa ojutuu si nnkan ti awọn ilu n fẹ lọwọ wọn.

O tẹnu mọ ọn pe asiko ti to ki awọn araalu taji ninu oorun ti wọn n sun ki wọn ya ara wọn lọgbọn ki wọn si mọ iyatọ ninu kijipa ati awọ ẹran nipa iṣẹ ti ọkọọkan ẹka ijọba n ṣe ko too di pe wọn yoo maa gbe Ojo fun Aina.

Ninu iṣẹ iwadii ti ajọ to n ri si gbigbogun ti iwa ajẹbanu ati jẹgudujẹra (ICPC) ṣe nipa mimoju to awọn iṣẹ akanṣe ni ẹsẹ kuku kaakiri ti awọn aṣofin ṣe fihan pe ẹbu lasan ni.

Nigba ti Aarẹ ajọ yii, Ọjọgbọn Bọlaji Owasanoye gbe aabọ iwadii yii jade lo sọ pe  awọn araalu, ni pataki julọ awọn ara ẹsẹ kuku ko ri ohun aritọka si nipa owo tabua ti awọn aṣofin sọ pe awọn ti na lori iṣẹ akanṣe ni agbegbe wọn.

Yoruba bọ, wọn ni agbọn n sẹ, ikamudu n sẹ, oju oloko ree gudugbugudugbu yii. Ọjọgbọn Owasanoye sọ pe ni nnkan bii ọdun mẹwaa sẹyin, nnkan bii tiriliọnu Naira kan ni awọn aṣofin wọnyi ti sọ pe awọn na ti ko si si ohun alaramọnda kankan to ṣe e tọkasi pe wọn dan wo laṣa nipa akanṣe iṣẹ ni ẹsẹ kuku.

Bi awọn aṣofin kan ṣe n sọ pe awọn ko tapa si ofin nipa owo akanṣe ti ile igbimọ n fun awọn ni awọn mi-in ni ko ri bẹẹ. Ṣugbọn ohun to daju ṣaka ni pe ṣe lo da bii ẹni pe awọn aṣofin wa niluu Abuja ko ri ti araalu to yan wọn sipo ro bi ko ṣe pe ọlọmu da ọmu iya rẹ gbe ni ohun ti wọn n ṣe. Eyi  ni awọn lameetọ ilu kan pe ni  lilu wọn ara ilu ni  jibiti tutu!

 

Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, 'Abiku' si ede Yoruba.