Ànfààní ríra oúnjẹ lówó pọ́ọ́kú ṣì n tẹ̀síwájú l'Ékòó-Sanwó-Olú
Ọlaide Gold
Kiiṣe aṣiiri to bo mọ pe ọwọngogo gbodekan latari bi ẹkunwo epo pẹntiroolu ṣe kọwọrin pẹlu owo dọla ilẹ okeere to po owo naira mẹrẹ.
Awọn nnkan wọnyii lo fa ọwọngogo saarin ilu leyi to mu ki ijọba ipinlẹ Eko ṣi ferese silẹ fun itura,akọọkọ ni ti ọja Sannde tijọba ṣi kaakiri ijọba ibilẹ kọọkan kawọn eeyan le ma lọọ ra ounjẹ lowo pọọku. Eyi to waye lonii Ọjọru Wẹside niwọn pe ni,Lagos State Intervention Programme 'Eko Cares' iyẹn iranlọwọ latọdọ ijọba ipinlẹ Eko si araalu gẹgẹ bi atura paapaa julọ lati kun awọn eeyan lọwọ nipa pipese ounjẹ funwọn lati koju ọwọngogo to gbodekan.
Ninu ọrọ ikinni kaabọ ẹ, nibi eto naa to waye lọfiisi ijọba ni Alahusa nilu Ikẹja, Ọgbẹni Gbenga Ọmọtọṣọ, Kọmiṣanna fun ọrọ iroyin nipinlẹ Eko lo ti sọ pe,eto naa wa ni ibamu pẹlu ileri ti gomina ṣe lati rii dajupe awọn eeyan ipinlẹ naa ko nii kigbe ebi lasiko ọwọngogo.
Kọmiṣanna naa ni,ṣaaju akooko yii ni Gomina Sanwo-Olu ti ṣi gbagede itaja kaakiri ijọba ibilẹ kọọkan nibi tawọn eeyan ti n ra ounjẹ ni ẹdinwo ni gbogbo ọjọ Sannde.O ni,erongba ijọba ni lati bu ororo itura si inira ti ọwọngogo dasilẹ nigboro.
Gomina Sanwo-Olu nigba to n bawọn araalu sọrọ nibi eto naa sọ pe, oun dupẹ lọwọ Ọlọrun fun anfaani aṣeyọri to n foun ni gbogbo igba. Gẹgẹ bi ọrọ rẹ 'Lasiko taa bẹrẹ sii ta ounjẹ ni gbogbo ọjọ Sannde, eyi taa ṣi kaakiri awọn ijọba ibilẹ, awọn kan ni ko le ṣeeṣe ṣugbọn si iyalẹnu wọn, Ọlọrun mu igbesẹ naa rọrun, a si ṣe aṣeyọri bẹẹ leto naa ṣi n tẹsiwaju. Ni bayii, a ti bẹrẹ ounjẹ pinpin lọfẹẹ ṣugbọn mo fẹ bẹ awọn aṣoju araalu pe kiwọn maṣe lọ bo ounjẹ naa mọ abẹ ibusun wọn, pinpin ni o bakan naa ni ki ẹ jẹ ko kari. Eto ti wa lati pin ounjẹ yii latọdọ awọn adari agbegbe,adari ẹsin atawọn adari ẹgbẹ kiwọn si ri dajupe nnkan lọ bo ṣe yẹ. Yatọsi iranlọwọ ounjẹ to bẹrẹ lonii, Sawnwo-Olu mẹnuba awọn eto to le ṣe araalu lanfaani tijọba ẹ ti bẹrẹ bii ilera Eko nibi tawọn araalu ti ni anfanni si iwosan lẹdinwo ni ọsibitu to ba sunmọ wọn. Ọkunrin akọọkọ nipinlẹ naa ni, ohun kan to daju nipe, ijọba oun ti ko akoyawọ ninu iṣẹ ilu, o ni titi dasiko yii, lawọn eeyan ṣi n ra ounjẹ lowo pọọku lawọn ọja aṣayan kaakiri ijọba ibilẹ wọn bakan naa wọn tun lanfaani si Ilera Eko atawọn ohun amayedẹrun mi-in tijọba ti pese fun wọn.
Awọn ounjẹ bii irẹsi,ẹwa ati gaari to
wa ninu apo iwọn kilogiramu mẹwaa lawọn eeyan gbelọ sile pẹlu idunnu.
Comments
Post a Comment