Ounjẹ tun ti de o! Dangote ti ko irẹsi ọfẹẹ wa fawọn olugbe Eko


Ọlaide Gold

Baagi irẹsi oniwọn kilogiraamu mẹwaa ni
alaga ajọ ẹlẹyinjuaanu, Aliko Dangote Foundation (ADF), Aliko Dangote, ko wọlu Eko gẹgẹ bi iranwọ lati koju ọwọngogo to gbodekan.

Irẹsi tiwọn niye ẹ to ẹgbẹrun lọna ọgọrin baagi ni ajọ naa ko wa sipinlẹ Eko fawọn araalu gẹgẹ bi atura lati koju ọwọngogo to suyọ latọdun to kọja latari afikun owo epo bẹntiro.

Eto iranwọ naa ti ajọ ọhun bẹrẹ lati ipinlẹ Kano ni Ọga agba ileeṣẹ Dangote, Dangote Industries Limited, Fatima Aliko-Dangote ti ṣalaye pe, gbogbo asiko aawẹ Ramadan lawọn maa n pin ounjẹ fawọn eeyan ni bonkẹlẹ ṣugbọn lati pe awọn ti Ọlọrun kẹ lawujọ nija kiwọn le ṣeranwọ fawọn araalu lasiko yii lo jẹ ki ileeṣẹ wọn ṣafihan tọdun yii faye ri.    
Aliko Dangote to jẹ alaga Aliko Dangote Foundation nigba to sọrọ nibi eto naa sọ pe, nnkan to ba ifẹ Ọlọrun mu
ni lati ṣeranwọ fawọn alaini lasiko tiwọn nilo rẹ. O ni,ipinlẹ Eko lo ṣikeji lẹyin tileeṣẹ wọn ti pin irẹsi baagi oniwọn kilogiraamu mẹwaa ẹgbẹrun lọna Ọgọfa nipinlẹ Kano. Irẹsi naa lo ṣeleri pe o ma tẹ awọn araalu lọwọ latọdọ awọn ajọ ẹlẹyinju aanu,awọn adari ẹsin igbagbọ ati musulumi atawọn adari agbegbe.
Gomina Babajide Sanwo-Olu ninu ọrọ tiẹ,dupẹ lọwọ ileeṣẹ Dangote fun ọwọ iranwọ to na sawọn araalu lai wo ẹsin tabi ẹya, o tun fasiko naa dupẹ lọwọ Fẹmi Ọtẹdọla ẹni to kọwọrin pẹlu Dangote fun iranwọ toun naa ti ṣe fawọn eeyan.
Sanwo-Olu ni, manigbagbe ni akitiyan ti ileeṣẹ Dangote ṣe fawọn araalu lọdun 2020 lasiko arun Korona bakan naa lọkunrin naa ko yee nawọ iranwọ sawọn eeyan latigba naa.

  

Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, 'Abiku' si ede Yoruba.