O ma ṣe o! Wọ́n ju òkú obìnrin kan sábẹ́ bírììjì ní Ṣagamu lẹ́yìn tí wọ́n yọ ẹyà ara ẹ̀ lọ


O ma ṣe o! Wọ́n ju òkú obìnrin kan sábẹ́ bírììjì ní Ṣagamu lẹ́yìn tí wọ́n yọ ẹyà ara ẹ̀ lọ

Johnson Akinpẹlu

 

Ariwo ikunlẹ abiyamọ lawọn eeyan ọja to wa ni abẹ biriji to wa ni Sabo, niluu Ṣagamu, nipinlẹ Ogun, n ke nigba ti wọn ṣadeede ri oku obinrin kan ti wọn sọ pe o ṣe e ṣe ko jẹ pe awọn ọmọ yahoo ni wọn waa gbe sibẹ lẹyin ti wọn ti yọ nnkan ti wọn nilo lara ẹ.

Gẹgẹ bi iwadii wa, laarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja, ni wọn ri oku obinrin naa nibi ti wọn tẹ ẹ si nilẹẹlẹ labẹ biriji, ti wọn fa ọyan ati abẹ ẹ lọ, eemọ iru kileleyi lawọn to rin si akoko n pariwo, bẹẹ ni ẹru ba wọn lati sunmọ.

Ohun kan tawọn eeyan n sọ ni pe awọn ọmọ yahoo ni wọn loo lati fi ṣetutu ọla wọn, nitori ti ko ba jẹ bẹẹ wọn ko ni fa abẹ ati ọyan ẹ lọ. Wọn sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ pe lara awọn obinrin ti wọn ti fi owo fa mọra ni, ko to di pe wọn gba ẹmi ẹ lojiji.

Lẹyin bi wakati meloo kan ni wọn ranṣẹ pe awọn ọlọpaa lati waa wo nnkan to ṣẹlẹ naa. Amọ titi di akoko yii, ko sẹni to le sọ pato ibi ti obinrin naa ti wa boya ọmọleewe lọmọbinrin naa ati tabi aṣẹwo.

Awọn ọlọpaa Ṣagamu yii ni wọn sọ pe wọn ṣeto bi wọn ṣe gbe obinrin naa kuro labẹ biriji, ti wọn si gbe e lọ si mọṣuari. 

Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, 'Abiku' si ede Yoruba.