Nnkan dé! Ìyàwó pásítọ̀ figbe ta: Ọkọ mi kó àtọ̀sí ràn mí, mi ò fẹ́ ẹ mọ́•Ẹ má dá a lóhùn, alágbèrè ni, ẹ tú wa ká – Pásítọ̀
Adesọla Adunni
Obinrin onisowo nla kan niluu Ado Ekiti, iyaafin Motunrayo Bayo-Famoroti lo ti rọ ile-ẹjo giga kan to fikalẹ siluu Ikere-Ekiti lati tu igbeyawo rẹ ọlọdun mẹrinla ka, pẹlu gbajugbaja oniroyin nni, Ọgbẹni Bayo Famoroti, latari ẹsun iwa agbere ati ija ajakudorogbo ninu ile wọn.
Iyaafin Bayo-Famoroti ninu iwe ẹbẹ ti agbejoro rẹ, Ọgbẹni Temitope Ọmọtayọ, kọ siwaju ile-ẹjọ nipa iwa ọkọ rẹ yii, lo ti salaye pe, bi ọkọ ohun se lu oun ni ilukulu bii asọ ofi lojoojumọ lo jẹ ki oun fi igbeyawo oun silẹ loṣu kẹrin ọdun 2022, lojuna ati doola ẹmi oun lọwọ iku aitọjọ.
Olupẹjọ naa to fẹsun kan ọkọ rẹ, to ma n ṣe ọpọlọpọ eto nipa ọrọ idile ati ilana ẹsin lori i redio kaakiri lati gba awọn idile ni imọran, ni iyawo rẹ yii tun bọ fẹsun kan pe, oun ko arun ibalopọ lara ọkọ oun nipasẹ iwa panṣaga rẹ pẹlu awọn obinrin ajeji to jẹ pe se lo n gbe-dudu gbe-funfun lasiko tawọn dijọ wa papọ.
Obinrin naa ninu iwe ipẹjọ rẹ niwaju Ile-ẹjọ tunbọ sọ pe, oun ti setan bayii lati jawe ikọsilẹ fun ọkọ oun, bẹẹ lo salaye ifẹsunkan onigun mẹta ọtọọtọ to gbe igbeyawo naa sanlẹ to ni ko le latunto mọ, pe, iwa aibikita, ikọlu lemọlemọ ati iwa agbere lo mu ki igbeyawo naa su oun patapata.
Iyaafin Bayo-Famoroti ni igbeyawo ti oun se pẹlu ọkọ oun tojẹ Ajihinrere ninu ijọ Anglican ẹkun Ekiti, lo wa nibamu pẹlu ofin titi di asiko ti awọn fẹẹ pinya yii. Igbeyawo naa lo ni awọn se lọjọ kọkanlelogun osu kọkanla ọdun 2009 tawọn si tipasẹ rẹ bi ọmọ meji.
Obinrin naa ni awọn ọmọ naa lọkan ninu wọn ti gbọgbẹ latari ẹbẹ igbagbogbo peki baba wọn dẹkun ilukulu ati iya to fi n jẹ ẹ nigbati wọn sijọ wa papọ.
O fi kun un pe awọn ọmọ meji naa lo ti n gbe pẹlu oun latigba naa, bẹẹni baba wọn ko figba kan da si jijẹ mimu awọn ọmọ naa, to fi mọ eto inawo ati ayẹwo wọn lati osu karun-un, ọdun 2022.
O ni lasiko kan, ọkọ ohun fi ẹrọ POS fọ oun lori, eyi to mu ki wọn gbe oun digbadigba lọsi ileewosan fasiti tipinle Ekiti fun itọjubi latari ifarapa naa, bẹẹni loun gba iwe esi ọgbẹ naa gẹgẹ bi ẹri nile-ẹjọ.
Lara awọn idẹrun ti olupẹjọ naa n bẹ ileẹjọ fun nipe, oun ni wọn igbati olujẹjọ ko ti gbe igbesẹ atunto fọpọ, ọdun sẹyin, ohun fẹ ki wọn tu igbeyawo naa ka patapata, k iwọn si yọnda anfaani foun lati fi awọn ọmọ naa toun ti n tọju si sakani oun sibẹ nitori ọjọọla wọn lewu bi wọn ba wa lọdọ baba wọn ti ko figba kan beere wọn. O ni ki ile-ejọ tunbọ pasẹ fun olujẹjọ naa lati ma ṣe kọlu oun lọna kan tabi omiran nibikibi, to fi mọ idẹruba tabi pẹgan rẹ.
Arabinrin naa ko sa i fi awọn aworan ikọlu ibi ti ajihinrere naa ti fiya jẹ ẹ pẹlu ọgbẹ han, gẹgẹ bi ẹri lati tu igbeyawo naa patapata, bẹẹni ile-ẹjọ ti gba lati bẹrẹ igbẹjọ lori ikọsilẹ naa ọjọ kẹẹẹdogun Oṣu Kẹrin, ọdun yii.
Amọ sa, Nigba tí Ajiyinrere Bayo Famoroti, n fesi si ifẹsun kan naa nipasẹ agbẹjọro ẹ, Dokita Michael Afọlayan, ọkọ iyawo tako ẹsun iwa-ipa, ija abẹle ati iwa pansaga ti iyawo rẹ fi kan an.
O tẹsiwaju pe oun ko figba kan kọlu u, tabi huwa aisedeede pẹlu olupẹjọ, to jẹ iyawo rẹ gẹgẹ bi bo ṣe fẹsun kan an, nigbogbo igba tawọn fijọ gbe papọ, nitoripe nipa iwa ifarada loun fi n gbe pọ pẹlu ẹ.
Ajiyinrere Famoroti ṣalaye pe ko sigba kan tabi asiko kankan ri ninu igbeyawo oun pẹlu olupẹjọ ti aaye si silẹ lati tẹle obinrin ajẹji kankan, bẹẹ loun ko figba kan ṣafihan obinrin ajeji gẹgẹ bi iyawo tuntun si Olufisun, bẹẹni ko figba kan ri pe oun si akiyesi boya o kẹẹfi iwa palapala lọwọ oun ri, toripe ajiyinrere to lorukọ niluu loun i se.
Gege bo ti wi, oun fi to iyawo oun leti nipa awọn ọmọ ohun meji tohun ni latọdọ obinrin miran kawọn too ṣegbeyawo rara, awọn ọmọ mejeeji ọhun ni akọbi tipe ọmọ ogun ọdun, ti ikeji sijẹ ọmọ ọdun mẹrindinlogun bayii.
Ọkunrin yii fẹsun kan Olupẹjọ pe, se lo bẹrẹ si ni i gbe aworan ara rẹ pẹlu ọkunrin ajeji kan, ẹni to pe ni akẹgbẹ ẹ nigba ti wọn fijọ wa nile-iwe giga sori ẹrọ ayelujara. O tunbọ fẹsun kan iyawo rẹ pe, ọpọ igba lo ma a n gbe awọn ọkunrin ajeji yii wa sinu ile wọn la i jẹ ki oun mọ tẹlẹ, bẹẹ lo ma n sọ pe awọn ọrẹkunrin tawọn jọ kawe pọ ni wọn nigbogbo igba
O fi kun idahun rẹ si ẹbẹ olupẹjọ pe ṣe lo ko awọn ọmọ lọ lai faaye silẹ lati yọju wo wọn lati igba naa to ti lo wọn awọn ọmọ naa pamọ fun oun.
O fi kun ọrọ pe gbogbo igbesẹ toun mo loun ti lo nipa akitiyan lati mu idile naa pada bo sipo, ṣugbọn to je pe pabo lo ja si, lẹyin tawọn agbaagba, aladugbo, ijọ Ọlọrun ti da si ọrọ naa. Bayii loun naa bẹ ile-ẹjọ pe ki wọn kuku tu igbeyawo naa ka lori alaye pe atunto rẹ kole se rẹẹgi mọ, sugbọn to be ile-ẹjọ pe ki wọn yọnda anfaaani lati mọ ibi tawọn ọmọ wa fun oun, ni Pataki julọ lawọn ọjọ isinmi laarin ọsẹ.
Comments
Post a Comment