Ayajọ awọn obinrin lagbaye:Sanwo-Olu ṣeleri ipin dọgba-n-dọgba
- Get link
- X
- Other Apps
Ọlaide Gold
Ayẹyẹ ayajọ awọn obinrin lagbaye min igboro Eko titi lonii ọjọ kẹjọ oṣu kẹta, ẹka ileeṣẹ ijọba to n ri sọrọ awọn obinrin ati idojutoṣi iyẹn Ministry of Women Affairs & Poverty Alleviation (WAPA) lo ṣe kokaari eto naa.
Eto pataki naa ti wọn pe akọle ẹ ni ' Count her in: Accelerating Gender Equality Through Economic Empowerment, iyẹn kika ọmọbinrin yẹ fun igbelewọn idọgba nipasẹ ọrọ aje eyi to waye ni ipagọ Mobọlaji Johnson to wa ninu papa iṣere Onikan l'Ekoo, nibẹ lawọn eekan ninu oṣelu atawọn alẹnulọrọ lawujọ ti pejupẹsẹ ba awọn obinrin ṣajọyọ ayajọ wọn.
Ninu ọrọ ti adari awọn obinrin ẹgbẹ APC, Ọnarebu Jumọke Ọkọya-Thomas sọ lo ti ki gomina ipinlẹ Eko,Ọgbẹni Babajide Olushola Sanwo-Olo, igbakeji ẹ, Ọmọwe Ọbafẹmi Hamzat atawọn iyawo wọn kaabọ sibi ayẹyẹ naa, o sọ nipa ipa ti obinrin n ko lawujọ ati idi ti ipin idọgba fi gbọdọ wa ninu ohunkohun to ba jẹ mọ takọtabo.
Bakan naa lọmọ ṣori pẹlu ọrọ ti oludanilẹkọọ ọjọ naa, Ọjọgbọn Mopelọla Ọmọegun sọ, o ni,ipa pataki ni obinrin n ko ninu idanilẹkọọ awọn ọmọ wọn lati inu ile nitoripe,ẹkọ akọọkọ ni eyi tọmọ kọ
latẹniu iya rẹ, o tẹsiwaju pe; ẹkọ iwe kika nikan kọ lo le sọ ọmọ di eeyan pataki lawujo nitoripe latilẹ ni obi ti gbọdọ kọ ọmọ rẹ ni ohun ti o tọ ki ọmọ naa le mọ bi yoo ti ma wu iwa lawujọ.
Alaga igbimọ to n mojuto ọrọ awọn obinrin ati ironilgbara nile aṣofin Eko,
Ọnarebu Ọmọlara Oyekan-Olumẹgbọn ninu ọrọ tiẹ sọ pe, akori kan ni ko jẹ amurele fun gbogbo obi ati alagbatọ fawọn ọmọbinrin wọn, o ni ki wọn maa sọ pe ' Ma a ka ọmọbinrin kun,ma a nawo le e lori bẹẹni ma a ran an lọwọ lati dagba soke'. O ni iwuri ni gbolohun naa yoo jẹ fawọn ọmọbinrin lati tẹsiwaju ninu ohun rere.
Iyawo gomina ipinlẹ Eko to tun jẹ iya ọjọ naa,Abilekọ Ibijọkẹ Sanwo-Olu gboṣuba kare fun gbogbo obinrin lagbaaye fun akitiyan wọn lori idagbasoke awujọ bakan naa lo gbawọn nimọran pe ki wọn rii daju pe wọn ṣe deede ninu iṣẹ wọn kawọn ọkunrin ma fọwọ rọ wọn sẹyin lawujọ.
Igbakeji gomina ipinlẹ Eko,Ọmọwe Ọbafẹmi Hamzat lo gbẹnu gomina sọrọ nibi ayẹyẹ naa, o ki awọn obinrin ku ayẹyẹ ayajọ naa bakan naa lo gboṣuba kare fawọn ikọ to jẹ ki eto naa waye,ko ṣai gba wọn nimọran lati tẹsiwaju sii ninu ohun rere,O ni, ipin ọgbọọgba tawọn obinrin n tẹnumọ yala ninu oṣelu tabi lẹnu iṣẹ ijọba ko le waye laisi ifọkansin nitoripe awọn ọkunrin ti wọn fẹ le ba paapaa ko duro.
Lakotan,Hamzat loun ba gbogbo obinrin ti ayẹyẹ tọun yii ṣoju ẹ yọ bẹẹ lo gba a ladura pe eyi to n bọ yoo dun ju bẹẹ lọ.
- Get link
- X
- Other Apps
Comments
Post a Comment