Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀: Iná ti jó dórí kókó
Yoruba bọ wọn ni ọrọ lo ba mo ko mo ro wa, ti ọmọ odo ba si na iya rẹ lasan kọ, bi aja ba n gbo, aja ya ri nnkan ni. Ọrọ awọn ajinigbe ni akoko yii ti di irawọ ọsan eyi ti o di apewo fun gbogbo mutu-muwa. Laipẹ yii ni awọn onisunmọmi yii ji awọn ọba gbe laafin ti wọn si ṣeku pa awọn kan nipinlẹ Ekiti ati Kwara.
Laluri to de ba awọn ara ilu yii lo tun ru soke ipe fun ọlọpaa ipinlẹ eyi ti yoo moju to eto aabo ilu ni ipinlẹ onikaluku. Bi ọpọlọpọ awọn ara ilu ṣe n pariwo fun ọlọpaa ipinlẹ ni awọn kan n sọ pe eleyii ko pọn dandan ati pe ilu to le, ti ohun gbogbo di goolu lọja, lo mu ki iwa ọdaran bii ka jinigbe fi di meji eepini laarin ilu.
Ohun ti o yani lẹnu ni ti awọn oloṣelu to fẹẹ sọ ọrọ naa di yẹbutu ni pataki julọ awọn ọmọ ẹgbẹ Alaburada (PDP), ti wọn fi ojoojumọ pariwo pe ọlọpaa ipinlẹ lo le jawe gbejẹ fun awọn ajinigbe nitori irufẹ awọn ọlọpaa yii mọ adugbo ati ileto wọn dajudaju ati pe ti wahala kan ba ṣẹlẹ,kia ni wọn yoo mọ awọn to ṣe agbatẹru iru iwa bayii.
Fun ọdun mẹrindinlogun ti PDP fi wa nijọba apapọ laye aarẹ Goodluck Jonathan ati Oluṣẹgun Ọbasanjọ,wọn ko ri ọrọ ọlọpaa ipinlẹ ro bi gbogbo ilu ṣe pariwo ni akoko yii to. Ohun iyalẹnu ati itiju lo jẹ laipẹ yii ti Ọbasanjọ waa n pariwo kiri pe ọlọpaa ipinlẹ lo le yanju ọrọ eto aabo to mẹhẹ lorilẹede yii. Ṣe Yoruba bọ wọn ni a ki i tori pipa jẹ ra Ayekootọ sile, ti ko ba le ṣe ofofo, alabosi ẹyẹ ni.
Ohun ti awọn lameetọ ilu n sọ ni pe ṣe lo da bii ẹni pe awọn oloṣelu n tan awọn ara ilu jẹ lori ọrọ ọlọpaa ipinlẹ ni. Ile aṣofin kẹsan-an l’Abuja jiroro gidigidi lori aba boya kii ọlọpaa ipinlẹ wa tabi ko ma si, o ṣeni laaanu pe ọgọọrọ awọn aṣofin to ti Oke-Ọya wa lo koro oju si aba yii ti wọn si fi ote le e pe aba naa ko le waye ati pe Naijiria ko ti i dagba fun ọlọpaa ipinlẹ.
Ni idakeji ẹwẹ, nigba to ku diẹ ki saa aarẹ Muhammadu Buhari tẹnu bepo lọdun 2022, awọn ẹgbẹ kan ti wọn pe ara wọn ni ẹgbẹ gomina to wa lati Oke Ọya (Northern Governor Forum), sọ pe ki wọn se atunto si iwe ofin ilẹ wa ki aaye le gba ọlọpaa ipinlẹ, eyi to jẹ pe ohun lo le yanju iṣoro eto aabo to mẹhẹ nigba naa.
Aba ti awọn gomina yii da yii waye nigba ti ilu ko fararọ ni agbegbe Oke- Ọya ti awọn onisunmọmi sọ adugbo yii di ibugbe wọn, ọpọlọpọ awọn alaiṣẹ niluu ni wọn ko lọ si igbekun, ti awọn kan si wa nibẹ di akoko yii. Akoko yii ni Buhari yan awọn igbimọ tẹ-ẹ-koto ninu awọn ọmọ ẹgbẹ Onigbaalẹ (APC), eyi ti gomina ana nipinlẹ Kaduna, Mallam El-Rufai ṣe oludari lati ri i pe aba yii di ofin nileegbimọ aṣofin.
Ṣugbọn o ṣeni laanau pe ṣe ni awọn aṣofin ti a n tori wọn gbaawẹ n jọsan, gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ PDP to wa lati Oke-Ọya ni wọn gbogun ti aba yii ti wọn ko si gba a wọle, eyi to mu ki aba ati erongba fun ọlọpaa ipinlẹ to yẹ ko wọnu atunto iwe ofin wa di ẹti ati ohun a-fi-sẹyin bii igba ti eegun ba fi aṣọ.
Ṣe ẹkọ ko ti waa foju mimu han bayii ati pe ọpọlọpọ awọn aṣofin ti awọn araalu dibo yan lati lọọ ṣoju wọn l’Abuja ko ri tẹnikẹni ro bi ko ṣe imọ ara tiwọn nikan. Akoko to yẹ ki gbogbo wọn gbimọpọ lati gbe igbesẹ akin lori ọrọ aabo ilu, ṣe ni wọn de fila-ma-wo-bẹ, ti wọn si fi ọrọ ilu ta ayo ọlọpọn, eyi jẹ, tọhun ko jẹ.
Pẹlu gbogbo idiwọ yii, awọn gomina kan gbe igbesẹ akin lati pa ọrọ iwe ofin ti, nigba ti iku awọn ajinigbe n wọle tọ awọn eeyan wọn bii meji eepinni. Lẹyẹ o sọka ni awọn gomina ipinlẹ Iwọ-Oorun ṣeto ikọ aabo awọn Amọtẹkun, eyi ti awọn akẹgbẹ wọn l'Oke-Ọya koro oju si ti wọn si sọ pe ki ijọba apapọ ma ro wọn lagbara lati le koju ipenija to ba doju kọ wọn.
Lẹyin iṣẹlẹ iṣekupani to waye niluu Ọ̀wọ̀, nipinlẹ Ondo, eyi ti awọn Fulani ya wọ ile ijọsin loju mọmọ, ti wọn si ṣeku pa ọpọlọpọ eeyan ti ogunlọgọ si fara pa yanna-yanna ni oloogbe gomina Rotimi Akeredolu ro awọn Amọtẹkun ni agbara diẹ ki wọn ma ba a di Amọtẹkun inu iwe lasan.
Ohun to tun jẹ kayeefi ninu ọrọ to wa nilẹ yii ni ilu Abuja ti awọn onisunmọmi yii waa sọ di ikoko ọbẹ wọn, to jẹ pe ojoojumọ ni iṣẹlẹ agbọ- kawọ-leri n ṣẹlẹ nipa ajinigbe, bẹẹ ni ọpọlọpọ ẹmi lo ti ṣofo.
Lakooko yii, awọn ilu-mọ-ọn-ka agbẹjọro to ti fi gbọọrọ jùẹka ninu imọ ofin ti sọ pe ko si ọna abayọ kankan ju pe ki Naijira pada si ẹsẹ aarọ, ki wọn si gba ọlọpaa ipinlẹ laaye ti wọn ba fẹẹ fẹdọ lori oronro.
Ogunna gbongbo ninu imọ ofin, Amofin Wọle Ọlanipẹkun, ti sọ pe ẹbu ni iwe ofin ti Naijiria gbe lọwọ ati pe ti wọn ba ju ada soke nigba igba, pẹlẹbẹ ni yoo fi le lẹ. O fi kun ọrọ rẹ pe ti ko ba si atunto iwe ofin ilẹ wa, yoo kan da bii pe eeyan yín agbado sẹyin igba ni.
Erongba rẹ ko yatọ si ti Amofin Olisa Agbakoba, ẹni to mọ toju-tẹyin ofin, sọ pe akoko naa ti to lati tun iwe ofin ilẹ wa kọ eyi ti yoo faaye gba ọlọpaa ipinlẹ, ati pe ti a ko ba tete gbe igbesẹ yii, ṣe lo da bii pe a n sun ọjọ ibi siwaju.
Bo tilẹ jẹ pe gomina ipinlẹ lmo, Hope Uzodimma, koro oju si dida ọlọpaa ijọba ipinlẹ silẹ , ninu ero tirẹ pe o loju awọn ipinlẹ to le rowo na lori iru ikọ bẹẹ, ṣugbọn awọn lameetọ ilu sọ pe ṣe ni gomina yii n pala lẹnu ni ati pe ko mọ nnkan to n sọ.
Wọn la a loyẹ pe gbogbo owo akanṣe fun aabo ilu, eyi ti awọn gomina n gba ni loṣooṣu ni ipinlẹ wọn ki i ṣe owo ti wọn ni ki wọn ko sinu asunwọn wọn fun igbadun ara wọn ati ẹbi wọn bi ko ṣe ki wọn fi pese aabo to nitumọ fun awọn araalu.
Akoko ree ki Aarẹ Bọla Tinubu wa wọrọkọ fi ṣada lori ọrọ to wa nilẹ yii, ko si gbe igbesẹ akin eyi ti yoo fopin si awuyewuye to n lọ lọwọ lori ọrọ ọlọpaa ipinlẹ .Ọrọ ti pesi jẹ ni akoko yii, afẹfẹ to si kaṣọ niyara ni, ki ẹni to wọ tiẹ sọrun ma jafira. Bẹẹ ni afẹfẹ to n daamu ologi, o ti sọ telelubọ dofo.
Comments
Post a Comment