Tírélà sọ ìjánu rẹ̀ nù, ló bá já wọ inú agboolé lọ
Kayọde Ọmọtọṣọ
Niṣe lori ko ọpọlọpọ awọn eeyan yọ lọsan-an ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii nigba ti ọkọ tirela Dangote kan to ko simẹnti ṣadeede sọ ijanu rẹ nu to si ja wọ inu adugbo Isẹrin,to wa niluu Iṣẹyin,nipinlẹ Ọyọ, lọ.Akọroyin wa gbọ pe ohun ọkọ tirela yii sọ ijanu rẹ nu ni,lẹsẹkẹsẹ ti iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ si ni awakọ tirela ọhun ati ẹni to tẹle e ti juba ehoro.
Comments
Post a Comment