Ijọba ipinlẹ Eko pin irinṣẹ ọfẹẹ fawọn to ṣẹṣẹ kọṣẹ pari
Ọlaide Gold
Ipinlẹ Eko tun dẹẹrin pẹẹkẹ awọn araalu laipẹ yii, awọn eeyan tiwọn fẹẹ to ẹgbẹrun mejila nijọba ro lagbara. Lọjọ Iṣẹgun Tuside ni ironilagbara naa ti waye ninu gbọngan nla Blue Roof to wa lojuna Agidingbi nilu Ikẹja, Ṣeni inu awọn tiwọn jẹ anfaani ironilagbara naa n dun ṣẹnkẹn tiwọn si gboṣuba kare fun gomina ipinlẹ naa, Babajide Sanwo-Olu.IIe ẹkọṣẹ tijọba gbe kalẹ iyẹn Skill Acquisition Centres mọkandinlogun to wa kaakiri nipinle naa ni wọn ti yan awọn tiwọn ro lagbara ọhun.
Latọdun 2019 nijoba ti gbe eto naa kalẹ, Lagos State Government Micro-Enterprise Support Scheme (MESI) niwọn pe e bẹẹ lawọn ẹgbẹẹgbẹrun ti kẹkọọ jade nibẹ tijọba si ro wọn lagbara.
Ironilagba naa tẹsiwaju lẹka ileeṣẹ ijọba to n moju tọrọ awọn obinrin iyẹn Ministry of Woman Affairs and Poverty Alleviation, WAPA, awọn ọdọ tiwọn le lẹgbẹrun kan lẹka ileeṣẹ naa ro lagbara. Irinṣẹ olowo iyebiye nijọba pese fawọn ti wọn kẹkọọ gboye jade lawọn ẹka ẹkọṣẹ naa, awọn irinṣẹ bii maṣiini tiwọn fi n yan guguru,maṣiini iṣerunlọṣọọ, maṣiini iranṣọ, maṣiini igẹrun, jẹnẹretọ, maṣiini tiwọn fi n ṣe ipapanu igbalode,ẹrọ tiwọn fi n ṣe gaari, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Gomina Babajide Sanwo-Olu ti igbakeji rẹ, Ọmọwe Ọbafẹmi Hamzat, ṣoju fun fi idunnu rẹ han gidigidi, o ni inu oun dun si eto naa atipe ojuṣe ijọba ni lati ma mu inu awọn araalu dun. Ninu ọrọ tiẹ, Kọmiṣanna to n bojuto ọrọ awọn obinrin, Abilekọ Cecilia Bọlaji Dada ni, eto naa jẹ akanṣe iṣẹ tijọba to ba fẹran araalu dọkan gbọdọ wo ni awokọṣe nitori iru eto bẹẹ ko nii faaye gba oṣi ati iṣẹ lawujọ wa, o gba awọn ti wọn jẹ anfaani naa nimọran pe ki wọn ṣamulo awọn irinṣẹ naa daadaa.
Comments
Post a Comment