Gbajabiamila fa ọsibitu tuntun atawọn iṣẹ akanṣe mi-in le Sanwo-Olu lọwọ l'Eko
Iṣẹ ya ni gomina Ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu fọrọ naa ṣe lọjọ iṣẹgun Tusidee, ọjọ keji ọdun yii. Ṣe lọ ṣefilọlẹ iṣẹ akanṣe mẹrin eyi to waye nipasẹ olori awọn oṣiṣẹ aarẹ,Ọnarebu Fẹmi Gbajabiamila.
Lara awọn iṣẹ akanṣe ti gomina ṣiṣọ loju ẹ ni ọsibitu jẹnẹra alaja mẹta, ọlọgọrin ibusun ti Gbajabiamila kọ sagbegbe Aralile ni Surulere.
Sanwo-Olu tẹwọgba ọsibitu naa lọwọ Gbajabiamila, ẹni to ti figbakan dari ileegbimọ aṣofin apapọ ilẹẹwa tawọn akọṣẹmọṣẹ onimọ iṣegun oyinbo yoo bẹrẹ sii da awọn alaisan lohun lati wakati naa lọ.
Ojuna mọto ti iwọn ẹ to kilomita kan ataabọ iyẹn ojuna Babs Animashaun ni Surulere naa wa lara iṣẹ akanṣe ti Gbajabiamila fa le gomina lọwọ eyi yoo mu ki lilọ bibọ ọkọ rọrun paapaa julọ fawọn ti wọn fẹ gba Surulere de Ikate ati agbegbe Orile bakan naa lo kọ gbọngan nla kan fawọn akẹkọọ yunifasiti ipinlẹ Eko iyẹn Lagos State University Ọjọọ ati ibudo igbafẹ Sam Ṣọnibarẹ Community Development Centre ni Surulere, eyi to tun ni ẹka ibudo idaraya loriṣiiriṣii atawọn aaye maraya miiran.
Sanwo-Olu ni itan o nii gbagbe Gbajabiamila atipe titi lae lawọn eeyan yoo ma royin igbesẹ ẹlẹyinju aanu tọkunrin naa gbe, o ni, yoo tun mu kawọn eeyan gbagbọ ninu ireti isọdọtun
Ṣaaju ko to di olori awọn oṣiṣẹ aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, Ọnarebu Gbajabiamila ti lọ ṣoju Surulere ẹkun kin-in-ni fun saa mẹfa nileegbimọ aṣofin l'Abuja, o bẹrẹ latori ọmọ ẹgbẹ to kere julọ titi to fi di abẹnugan ileegbimọ aṣofin.
Comments
Post a Comment