Emefiele: Ọmọdé tó ń jẹ èèwọ̀, tó bá yá, ohun tó ń bini kò ní í ṣaláì bini


Aṣe tootọ lowe awọn agba to sọ pe igba ki i tọ lọ bii orere, aye ki i tọ lọ bii ọpa ibọn. O fẹrẹ ma si eeyan kan ti ko da ẹni to n jẹ Emefiele mọ nipa ipa to ko nigba to wa nipo gomina ileefowopamọ apapọ.

Orukọ Emefiele ko ni i parẹ ninu iwe itan Naijiria nitori ipa to ko nigba to gbe ofin abaadi lati pa awọ awọn kan ninu owo ilẹ wa da si tuntun lai fi akoko  to niye lori lati gbe igbesẹ yii si i, eyi lo jẹ ki igbesẹ ọhun fori sanpọn to si mu inira ati idaamu ba gbogbo ẹka okoowo lorilẹ-ede yii.

Laipẹ yii ni igbimọ ti ijọba apapọ gbe kalẹ lati ṣewadii  lori awọn owo to poora  labẹ akoso Emefiele gbe aabọ iwadii rẹ kalẹ to si sọ pe ẹbọ n bẹ lẹru ọkunrin yii. Eyi to jẹ kayeefi ni awọn obitibiti owo ti ọkunrin yii ko pamọ si awọn banki bii ẹgbẹta niluu okeere  to si lo awọn alagata lati fi owo naa pamọ.

Yatọ si eleyii, Ọgbẹni Jim Obase, ẹni to ṣe iwadii lẹkunrẹrẹ naa jabọ pe gbogbo iṣẹ ti ko si ẹni to ran Emefiele lo jẹ funra rẹ gẹgẹbi ipo to wa ati pe ṣe lo n ṣe bii ọlọba eyi to mu ki oun ati awọn lọga-lọga nileefowopamọ naa ya owo tuulu sọtọ fun ara wọn gẹgẹbi ajẹmọnu .

O fi kun ọrọ rẹ pe ọpọlọpọ igbesẹ to jẹ mọ aṣiiri eto okoowo to yẹ ki Emefiele gba aṣẹ lọwọ Aarẹ Muhammadu Buhari lo da iṣẹ ara rẹ jẹ to si gbidanwo lati ṣe ohun to wu u lai beṣu-bẹgba.

Eyi to buru ju ninu gbogbo awọn aṣiṣe Emefiele gẹgẹbi iwadii naa ti ṣe gbe e kalẹ ni igbesẹ to gbe nipa ọrọ owo tuntun eyi ti wọn ṣe ni kumọ -kumọ nitori dipo ki owo naa wa laarin awọn araalu, awọn perete ni wọn n ri owo yii na, ti awọn kan si sọ ara wọn di baranda oniṣowo owo tuntun, eyi to sọ ọpọlọpọ awọn ti Emefiele  fẹ di olowo ojiji.

A oo ranti pe  ni kete ti Emefiele ti ri i pe oun ko ri ọwọ mu ninu ọrọ oṣelu ati pe ẹkọ ko ṣoju mimu fun oun mọ lo ti n wa gbogbo ọgbọn alumọkọrọyi ti yoo fi juba ehoro. Eyi lo mu ko dabaa ati fẹẹ lọọ kawe loke- okun, ṣugbọn ti aba naa di ofo.

Nigba to n sọrọ lori igbesẹ yii, Gomina ipinlẹ Zamfara, Ọgbẹni Bello Matawalle, sọ pe Aarẹ ko gbọdọ gba Emefiele laaye lati fi ilu silẹ nitori o ni ọpọlọpọ alaye lati ṣe nipa ipa to ko to fi sọ ọrọ aje Naijiria di meji eepini, yatọ si eleyii, o si ku nnkan bii oṣu mẹwaa ki saa rẹ tẹnubodo gẹgẹ bii oludari agba fun banki apapọ, ki waa lo n kan an loju lati juba ehoro?

Matawalle fi kun ọrọ rẹ pe o ti daju pe Emefiele ni aṣiiri to n bo ti ko fẹ ki yangba ọrọ rẹ fọ mọ oun lori lẹyin ti ijọba tuntun gbọpa aṣẹ ati pe ohun gbogbo to wa ni ikawọ rẹ lo ṣe lati ri i pe o dabaru eto idibo to kọja nipa fifi ara ni awọn araalu ati pe igbesẹ yii ti yi eto idokoowo ati eto kara-kata ni gbagede ọja si oju keji.

Ohun ti awọn lameetọ ilu sọ ni akoko yii ni pe Emefiele ti mọ gbogbo awọn itu to pa ati awọn idan orita to ro nipa owo ilẹ wa, bẹẹ ni ko ṣai mọ pe  ọmọde to n fi aarọ dẹsa ejo, ara iku lo n ya a.

Bo tilẹ jẹ pe awọn kan n sọ pe igbimọ ti ijọba apapọ gbe kalẹ yii lati tọpinpin gbogbo iwa ibajẹ to waye ni banki apapọ lasiko Emefiele ki i ṣe ile-ẹjọ ati pe ile-ẹjọ nikan lo le fi ote le e pe ọkunrin yii lẹbọ lẹru.

Ṣugbọn Yoruba lo sọ pe ohun ti a ko mọ ni a ko mọ, ẹni to n singba ko lowo lọwọ. Ko si gbogbo awọn ti idaamu ba nigba ọwọngogo owo ilẹ wa ati wahala to tẹyin owo tuntun yọ to le fi oju rere wo Emefiele.

Bo tilẹ jẹ pe ominira diẹ wa fun Emefiele lakooko yii, ohun ti awọn ọjọgbọn ninu imọ eto ọrọ aje n sọ ni pe nnkan ti bajẹ gidigidi ki wọn too si Emefiele lọwọ iṣẹ ati pe lai tẹ tufọ aja, ti eeyan ba fi oju inu wo awọn igbesẹ  ti gomina ile owo tẹlẹ yii gbe, ni pataki julọ nigba to deede gbe ọgọrun-un biliọnu Naira silẹ lati fihan pe oun yoo du ipo aarẹ orilẹ-ede yii lai kọwe fi ipo naa silẹ, tọhun yoo mọ pe oju lo ka oloro mọ gbagede ita.

O ṣeni laaanu pe ninu iporuuru ọkan lati ṣiṣọ loju mejeeji bii igba ti ajẹ ba n sọ ile Olodunmare eyi ti ijọba apapọ n ṣe lori ọrọ Emefiele, didi Bibeli nla dani ko le tan ọran to da silẹ yii rara. O ti ri oko ikun ko too lọ gbin ẹpa si i atipe o yẹ ko ti ri ọwọ ija nilasa pe bintin laye ati pe ọmọde to n jẹ eewọ, awọn baba wa ni ko mura si i, to ba ya, ohun ti n bini ko ni i ṣalai bini.

 

Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, 'Abiku' si ede Yoruba.