Àwọn ajínigbé: A fi ọmọ àparò sábẹ́, a ń gbin ọkà


Ko si wa ka tẹ tufọ aja lori ọrọ awọn ajinigbe ni akoko yii, o fẹrẹ ma si ibi ti wọn ko ti n ṣọṣẹ. Bi wọn ti n ji eeyan gbe ni ipinlẹ Kaduna, bẹẹ ni Abuja ko fara rọ, ti ipinlẹ Zamfara ko fi ẹdọ lori ororo eyi to mu ki awọn ara ilu maa pariwo pe o to gẹ, aludundun ki i darin.

Eyi to jẹ kayeefi ni ti jijigbe ọga agba kan lẹnu iṣẹ ijọba, Ọgbẹni Mansoor Al-kadriyar ati awọn ẹbi rẹ. Nibi ti aya ko awọn ọdaran yii de, wọn pa ọkan ninu awọn ọmọ rẹ ti wọn si fi awọn yooku sinu igbekun.Lai beṣu-bẹgba wọn fi kan-an-pa le e pe ko lọọ wa aadọrin miliọnu Naira wa ko too le ri awọn mọlẹbi rẹ gba pada.

Ṣe Yoruba bọ wọn ni itan inaki ni oju mi ko to o, ṣugbọn to ba ṣe ti ijimere baba ọbọ, mo mọ diẹ nipa rẹ. Ọjọ naa lo da bii ana yii ti awọn ika buruku yii ya wọ ile ijọsin niluu Ọ̀wọ̀ ti wọn si fi ọpọlọpọ ẹmi ṣofo, eyi to jẹ pe hanranhanran rẹ ko ti i kuro lara awọn ara ilu Ọwọ titi di akoko yii, bẹẹ ni gbogbo awọn ti aje iwa ika yii ṣi le lori ti ọwọ tẹ ko ti i ri idajọ to tọ si wọn.

Bakan naa, awọn mejila lati Yunifasi nipinlẹ Zamfara lo wa ni akoto awọn ajinigbe bayii, ti awọn bii ogun lati ilu Abuja ati agbegbe rẹ naa wa lakolo wọn ti awọn agunbanirọ mẹrin  lati ipinlẹ A’lbom naa ko gbẹyin ni ahamọ awọn ọdaran yii. Ojoojumọ ni awọn ẹbi wọn n pariwo si ijọba pe ki wọn jọwọ bawọn wa wọrọkọ ṣe ada lori ọrọ yii, ki awọn eeyan wọn  le yọ ninu ajaga ti wọn wa yii, ṣugbọn pabo lo ja si.

Ohun ti gbogbo eleyii n tọka si ni pe eto aabo ti mẹhẹ, bẹẹ ni o da bii ẹni pe agbara awọn  alaabo ilu ko fẹẹ ka ọrọ to wa nilẹ yii. Lọsẹ to kọja ni awọn ajinigbe yii ṣọṣẹ niluu Abuja. Ṣe omi kekere ni a le rẹ ila si, to ba ti di agbalagbulu omi, yoo gbe ila lọ.

Nigba to n sọrọ lori laaṣigbo ti awọn ajinigbe n da silẹ yii, ẹni to ti figba kan jẹ ọga agba ninu iṣẹ ọlọpaa ko too fẹyinti, Ọgbẹni Agboọla Oshodi-Glover sọ pe atunto gbọdọ de ba bi awọn agbofinro yoo ṣe maa doju kọ iṣoro awọn ajinigbe yii. O tẹ siwaju pe ijọba nikan ko le daya kọ inawo to wa nidii a n gbogun ti awọn ajinigbe, ṣugbọn ki ajọ kan ti ki i ṣe tijọba gbaradi lati dawojọ sinu osunwọn ti wọn yoo maa lo fun iṣẹ aabo ilu yii.

O sọ pe asiko ti to lati koju ipenija yii pẹlu awọn irinṣẹ igbalode eyi ti yoo ran iṣẹ iwadii awọn agbofinro lọwọ lati le doju ija kọ awọn ẹni ibi yii, nitori ti ọmọde ba gbọn ọgbọn kuku, iya rẹ yoo gbọ ọgbọn sinsin, to ba ku lẹẹrun, wọn yoo sin in sipado.

Ohun ti awọn lameetọ ilu lori eto aabo n sọ ni pe ko ma jẹ pe awọn ọdaran to fi tipatipa jade lẹwọn nigba kan ti ọwọ awọn ijọba ko ti i tẹ wọn lo waa sọ ara wọn di arisa ina, a ko ta giri ejo yii. Bẹẹ ni awọn miiran sọ pe aiṣe idajọ ododo to yẹ fun gbogbo awọn ti wọn ti mu to wa latimọle nipa iwa ajinigbe yala ki wọn yẹgi fun wọn tabi ki wọn sọ wọn si ẹwọn ọlọjọ gbọọrọ lo jẹ ki iwa buruku yii tun maa gbilẹ si i.

Ṣe bi awọn araalu yoo ṣe gba kamu lori ọrọ yii ree abi ọna abayọ wa? Ninu ero tirẹ, ẹni to jẹ onimọ kikun lori ọrọ aabo ilu, Ọgbẹni Chuks Maya, sọ pe ọrọ eto aabo ti kuro lori ijọba nikan bi ko ṣe ki onikaluku san ṣokoto rẹ ko le lati maa rin irin ifura bii ti aparo nitori iku to n pa ojugba ẹni, owe lo n pa fun ni.

Maya ni igbe aye awọn eeyan ati bi wọn  ṣe n ba awọn aladuugbo lo pọ pẹlu ki awọn eeyan maa nawo yafunyafun lawujọ yoo jẹ ki awọn ẹni ibi yii ri iru eeyan bẹẹ gẹgẹ bii ẹni ti wọn le  jigbe.

O tẹnu mọ ọn pe  asiko ti to fun awọn ipinlẹ kọọkan lati ra baalu a-yara-bii-aṣa eyi ti wọn yoo fi maa ṣọ inu igbo wọn, dipo fifi owo ara ilu ṣofo eyi ti ọpọlọpọ awọn gomina wọnyi n ṣe ati pe ipinlẹ kọọkan gbọdọ ni awọn to n ṣọ igbo wọn ti wọn n pe ni aṣọgbo nigbakan.

Gẹgẹbi ero tirẹ, wọn gbọdọ ro awọn aṣọgbo yii lagbara ki wọn si pese ibọn igbalode eyi ti wọn yoo fi koju awọn ọdaran yii ati pe inu igbo ni wọn yoo maa gbe. O fi kun un pe ti ipinlẹ kọọkan ba le ko ọgọrun-un ọkunrin to sangun-un jọ, ti wọn si fun wọn ni idanilẹkọọ lati ọdọ awọn ologun ki wọn too da wọn sinu papa, ni kete ti ijinigbe ba ti ṣẹlẹ, wọn yoo fi irinṣẹ igbalode mọ ibi ti awọn ajinigbe yii wa, ti wọn yoo si gbe pẹrẹgi kana pẹlu wọn.

Nigba kan ana ti awọn kan dabaa ọlọpaa agbegbe eyi ti yoo le ran awọn agbofinro lọwọ, oju ọtọ ni awọn kan fi wo o, ti wọn si gbogun ti awọn to dabaa yii. Njẹ jẹbẹtẹ ko ti gbe ọmọ le wa lọwọ bayii?  A fi ọmọdiyẹ sabẹ a n gbin ọka, ṣe adanu ati ofo kọ ni n gbẹyin iru igbesẹ yii?

 

Ohun to daju ni pe ọpọlọpọ ijiroro lori eto aabo ni ijọba ti ṣe laimọye igba, ṣugbọn ti ko tu irun kan lara awọn ọdaran yii, ti aṣọ ba ya jugbujugbu, ṣe la maa n ran jagbajagba ki o le ṣe e mu lọ sode. Akoko yii ko gba ijiroro rara bi ko ṣe igbesẹ eyi ti yoo so eso rere.

Ina ti jo dori koko, akoko ree fun Aarẹ Tinubu lati gbe igbesẹ akin lori ọrọ yii.Ọrọ awọn ajinigbe ti di atupa to fi ọsan tan, ti ko jẹ ki ọmọ araye foju rere wo oun. Ti ilu ba si n dun pami-n-ku, pami-n-ku, mẹlọmẹlọ la a fi n  jo o. Gbogbo ohun to ba gba ni ṣiṣe ni Aarẹ gbọdọ ṣe ki o si ni ipinnu to le koko bii oju ẹja lati de fila ma-wo-bẹ nipa fifi iya jẹ awọn ti ọwọ ba tẹ.

Ṣe Yoruba bọ wọn ni ti ọmọde ba sọ oko lu ni, ti a ba sọ idarọ lu u pada, ko buru ju, awọn ajinigbe ti pe sonso, o si yẹ ki wọn ri sonso lati ọwọ awọn agbofinro ki wọn le mọ pe iyan ti di atungun, ti ọbẹ si ti di atunse.

 

Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, 'Abiku' si ede Yoruba.