Àwọn afiniṣètùtù pa ọmọ ọdún mọ́kànlá tó n kiri ọjà•Wọ́n fipá bá a lòpọ̀, wọ́n tún yọ ẹyinjú rẹ̀ méjéèjì lọ


Kayọde Ọmọtọṣọ, Ibadan

 

Niṣe lawọn eeyan n bomi loju lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejilelogun,oṣu to kọja yii laduugbo Oke-Anu, niluu Ogbomọṣọ, nigba ti wọn kan oku ọmọdebinrin Hausa kan ninu ile akọku to wa laduugbo ọhun ti wọn si tun ti yọ ẹyinju rẹ mejeeji lọ. Iṣẹlẹ yii lo jẹ ki awọn eeyan maa rọ lọ sile ọhun lati foju wọn kan ohun to ṣẹlẹ.

GBÉLÉGBỌ́ gbọ pe Sumaya Kabiru, ọmọ ọdun mọkanla lọmọ to ṣagbako iku ojiji lairotẹlẹ yii n jẹ. Ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kejila, ni Sumaya gbe igba wara, eyi ti wọn tun n pe ni bẹskẹ, to n ta lori, o loun fẹẹ sare kiri ọja lọ gẹgẹ bii iṣe rẹ, ṣugbọn alọ rẹ ni wọn ri, wọn ko ri abọ, eyi to si jẹ ki ibẹru-bojo gba ọkan baba ati iya rẹ kan.

    Koda, jannajanna ni baba rẹ, ẹni to n ta maalu, sare gba ori redio lọ nibi to ti ni ki wọn ba oun kede pe oun n wa Sumaya, ọmọ oun to poora lojiji, pe ẹnikẹni to ba ri i ko fi to oun leti, bẹẹ lo si tun fi iroyin ohun to ṣẹlẹ yii to ileeṣẹ ọlọpaa leti pẹlu. Ẹnikan to sunmọ ẹbi yii ṣalaye fun akọroyin wa pe "nigba ti gbogbo igbiyanju rẹ ja si pabo lo tọ awọn aafa lọ, awọn ni wọn si fi i lọkan balẹ titi di Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to lọ lọhun-un pe ọmọ rẹ wa laaye, ṣugbọn ọjọ Ẹti, Furaidee, ni awọn aafa ọhun sọ fun un pe ami tawọn ri fihan pe ọmọ rẹ ti ku.

"Mo gbọ pe iya ọmọ yii naa la aala ri i loru Ọjọbọ, Tọsidee, mọju Furaidee, eyi lo si jẹ ki ẹru tu bọ maa ba iya rẹ. Ṣe lo bẹrẹ si i wa a kiri, o ni ọmọ oun o ki i kiri ọja kọja Kara Sabo si Oke-Aanu. Nibi to ti n wa a kiri lo ti de inu ile akọku kan ti oorun kan si fẹ lu u. Eyi lo fa a to fi wọ inu ile yii, ibanujẹ lo si jẹ fun un nigba to kan oku ọmọ rẹ. Ariwo ti iya yii pa lo ta awọn ara adugbo lolobo, nigba tawọn eeyan si debẹ ni wọn ri i pe wọn ti yọ ẹyinju, ọkan, ati awọn ẹya ara mi-in lọ."

      Awọn akọroyin wa ogbifọ kan to ba iya Sumaya sọrọ lasiko naa lo si sọ pe oun ti gba fun Ọlọrun. O ni "mo fa gbogbo wọn le Allah lọwọ, yoo si san wọn lẹsan ohun ti wọn ṣe."

Obinrin to ni ọmọ mẹwaa loun bi ṣugbọn meji ti jẹpe Ọlọrun bayii, ni pe nigba tawọn o ri Sumaya lawọn lọọ kede lori redio. O ni "a ṣe ikede lori redio a si tun sọ fun awọn aafa lati ba wa wa oju Allah ko ba wa ṣe e ni riri. Mi o le sun, mi o si le jẹun. Nnkan bii aago mẹwaa aarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to lọ lọhun-un ni mo tun fọkan gbadura si Ọlọrun ko ṣe e ni riri ti mo si bẹrẹ si i wa a kaakiri. Mi o ti i lọ jinna ti mo fi ri bata rẹ, bi mo ṣe bẹrẹ si i kan lu igbo ree pe boya o wa ninu igbekun kan to nilo iranwọ, ṣugbọn oku rẹ ni mo ri. Wọn ti yọ oju rẹ mejeeji lọ, wọn si tun yọ nnkankan nibi ọrun rẹ.Awọn ọlọpaa to wa ni o ṣee ṣe ko jẹ pe wọn fipa ba a lopọ ni. Niṣe ni oriṣiiriṣii eegun eeyan wa ninu ile yii pẹlu."

GBÉLÉGBỌ́ gbọ pe wọn ti gbe oku Sumaya lọọ sin, wọn si ti fi iṣẹlẹ ọhun to awọn ọlọpaa teṣan Owode, niluu Ogbomọṣọ, leti.

 


Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, 'Abiku' si ede Yoruba.